Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọwọ ajọ sifu difẹnsi, ẹka tipinlẹ Kwara, ti tẹ awọn afurasi mẹta kan ti wọn jẹ ọmọ ipinlẹ Adamawa, Buhari Joda, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, to jẹ dẹrẹba ati awọn meji miiran, ọmọọsẹ rẹ, Hamidu Joda, ẹni ọdun mejilelọgbọn, ati Buhari Aminu, ẹni ogun ọdun, lagbegbe Oko-Olowo, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara. Ẹsun pe wọn n gbe epo to yẹ ko wa fawọn araalu gba ibomi-in lọ ni wọn tori ẹ mu wọn.
Ọga agba ajọ ẹṣọ naa ni Kwara, Ibrahim Tukur, lo fi ọrọ naa lede fun awọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kejila yii, niluu Ilọrin. O ni awọn afurasi ọhun gbe epo bẹtiroolu to yẹ ki wọn gbe lọ si ipinlẹ Eko, wọn si gbe e lọ sileepo Ọladeji, lagbegbe Oko-Olowo, niluu Ilọrin.
Tukur ṣalaye pe Ikorodu, niluu Eko, lo yẹ ki wọn gbe epo naa lọ, ṣugbọn wọn lọọ ta a lọwọn gogo nipinlẹ Kwara. O fi kun un pe ajọ naa ti da awọn oṣiṣẹ sita lati maa mu eyikeyii kọlọransi ẹda ti wọn fẹ maa fara ni araalu nipa tita epo lọwọngogo tabi gbe e gba oko ibomiran lọ.
Alukoro ajọ naa ni Kwara, Ayẹni Ọlasunkanmi, sọ fun ALAROYE pe awọn afurasi mẹtẹẹta naa gba pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, sugbọn iwadii ṣi n lọ lọwọ. Lẹyin iwadii lo ni awọn yoo foju wọn ba ile-ẹjọ.