Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ajọ to n ri si lilo ati gbigbe oogun oloro nilẹ yii, (NDLEA), ẹka tipinlẹ Kwara, ti dana sun awọn oogun oloro to to bii biliọnu meji Naira, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla, ọdun yii, niluu Ilọrin.
Alaga ajọ naa, Buba Marwa, ti Muhammed Sokoto ṣoju fun nibi eto naa to waye niluu Ilọrin ṣalaye pe awọn oniruuru oogun to n lọ bii ẹgbẹrun lọna mẹrinlelogun ati mọkanle lẹgbẹta kilogiraamu ni wọn jo nina.
O gboriyin fun ajọ naa ni Kwara, fun bi wọn ṣe n fofin de awọn oogun oloro yii, o ni igbeṣẹ tootọ ni wọn n gbe lati ri i pe wọn fọ orile-ede Naijiria mọ lọwọ awọn to n lo oogun oloro.
Ọga ajọ NDLEA ni Kwara, Alaaji Ibrahim Saidu, sọ pe lara awọn oogun oloro ti wọn dana sun ni igbo, kokeeni ati bẹẹ bẹẹ lọ. O tẹsiwaju pe awọn ri aọn oogun naa gba lasiko ti ajọ naa n yide kiri.
O fi kun un pe awọn gbe igbeṣẹ naa lati ri i pe gbogbo awọn to n gbe tabi lo oogun oloro ko kuro ni Kwara, ti orukọ ipinlẹ naa yoo si kuro lara awọn ti wọn n lo oogun oloro.