Adewale Adeoye
Ajọ to n gbogun ti lilo ati gbigbe egboogi oloro nilẹ yii, ‘National Drug Law Enforcement Agency’ (NDLEA), ilẹ wa ti sọ ọ di mimọ pe awọn mẹrinlelọgbọn kan ninu awọn to n ṣowo egboogi oloro lọwọ awọn ti tẹ, tawọn si maa foju wọn bale-ẹjọ laipẹ yii.
Ọkan pataki lara awọn ọga agba ajọ naa ti ẹka ilu Abuja, Ọgbẹni Kabir Tsakuwa, lo sọrọ ọhun di mimọ fawọn oniroyin kan niluu Abuja, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejinlogun, oṣu, Karun-un, ọdun 2023 yii.
Ninu ọrọ rẹ ni ọga agba naa ti sọ pe o ṣẹ pataki pupọ fun ajọ naa lati lọ kaakiri aarin ilu Abuja bayii, lati maa fọwo ofin mu gbogbo awọn ọdaran ti wọn n ṣowo egboogi oloro, atawọn to n lo o, paapaa ju lọ, bi ijọba tuntun ṣe fẹẹ gba iṣakoso ijọba orileede yii.
O ni, ‘‘Ṣe la da ikọ akanṣe kan ta a pe ni ‘Operation Tsaro’ silẹ lọjọ kẹjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii. Ojuṣe ikọ naa ni lati maa lọ kaakiri aarin igboro ilu Abuja, ki wọn si maa fọwo ofin mu gbogbo awọn ọdaran ti wọn n ṣowo egboogi oloro, atawọn to n lo o. A ti lọ kaakiri aarin ilu naa, a si ti fọwọ ofin mu awọn ọdaran kọọkan tọwọ wa tẹ.
Lara awọn agbegbe ta a ti ri awọn ọdaran naa mu ni: Torabora, Dei-dei, Wuse Zone 4, Wuse Zone 3, Banex, Garki, Area 1, Gwarimpa, Karu, Gwagwalada, Kabusa, Kuchigoro ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O fi kun un pe, awọn kọọkan ti ọwọ awọn tẹ lawọn ti gbe lọ sile-ejọ, lati le lọọ jiya ẹṣẹ wọn.