NDLEA n wa tọkọ-tiyawo yii gidigidi, okoowo egboogi oloro ni wọn n ṣe

Adewale Adeoye

Ajọ to n gbogun ti gbigbe ati lilo egboogi oloro lorileede yii, ‘National Drug Law Enforcement Agency’ (NDLEA), ẹka tipinlẹ Eko, ti kede pe awọn n wa awọn tọkọ-taya kan, Ọgbẹni Kazeem Ọmọgoriọla Owoalade ati Abilekọ Rashida Ayinkẹ Owoalade

Ẹsun pe wọn n ṣokoowo egboogi oloro lati orileede Naijiria lọ silẹ India ni wọn fi kan wọn.

ALAROYE gbọ pe ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, lọwọ  NDLEA tẹ Ọgbẹni Imran Taofeek Ọlalekan, ti i ṣe ọmọọṣẹ wọn, lasiko to fẹẹ gbe kokeeni lọ siluu Oman, lorileede Qatar, lati papakọ-ofurufu Murtala Muhammad International Airport to wa niluu Ikeja nipinlẹ Eko, nibi ti ọwọ awọn agbofinro ti tẹ ẹ. Ọgbẹni Ishọla Isiaka Ọlalekan toun naa jẹ ọmọọṣẹ Alhaji Kazeem Ọmọgoriọla to n gbe lorileede India, lọhun-un lo pe Imran siṣẹ naa, ṣugbọn Imran nikan lọwọ tẹ, ọrẹ rẹ ti sa lọ.

Iwadii nipa awọn afunrasi ọdaran ọhun so eeso rere lẹyin nnkan bii ọsẹ marun-un ti NDLEA ti n wa wọn. Agbegbe Abule Ẹgba, nipinlẹ Eko lọwọ ti tẹ Hameed Abimbọla Saheed, lọjọ kẹrinla, oṣu Karun-un, ọdun yii, oun naa si  jẹ ọkan pataki lara awọn ọmọọṣe Alhaji Kazeem Ọmọgoriọla yii.

Saheed yii lo gba otẹẹli igbalode kan fun Imran, kọwọ too tẹ ẹ ni papakọ ofurufu Murtala Muhammad International Airport, lọjọ ti wọn mu un.

Alukoro ajọ NDLEA, Ọgbẹni Femi Babafemi, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sanndee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, sọ pe o ti pẹ tawọn tọkọ-taya naa ti wọn n gbe nilẹ India, ṣugbọn ti wọn n ṣowo egboogi oloro lorileede Naijiria ti wa lẹnu iṣẹ ti ko bofin mu yii ko too di pe ọwọ tẹ awọn ọmọọṣẹ wọn bayii.

Iwadii ti NDLEA ṣe fi han pe mọto kan ati ile meji ti wọn gba lọwọ awọn ọmọọṣẹ tọkọ-taya meji naa jẹ tawọn afurasi ọdaran ohun, ajọ naa si maa too kede rẹ pe ijoba orileede yii ti gbẹsẹ lẹ e lẹyin ti wọn ba gba aṣẹ nile-ejọ.

Atẹjade kan ti wọn fi sita lori iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti ṣalaye pe, ‘‘Mẹrin ninu awọn ọmọọṣẹ awọn afurasi ọdaran kan, Alhaji Kazeem Ọmọgoriọla, ẹni tawọn eeyan mọ si Abdul Qassim Adisa Balogun, ati iyawo rẹ, Abilekọ Rashida Ayinkẹ Owoalade, ẹni tawọn eeyan mọ si Bọlarinwa Rashida Ayinkẹ, lọwọ ti tẹ. Lasiko ti Imran fẹẹ gbe egbogi oloro kokeeni lọ siluu Oman, lorileede Qatar, ni wọn mu un ni papakọ ofurufu Murtala Muhammad International Airport.

‘’Saheed lo gba otẹẹli kan fun Imran ati ọrẹ rẹ lagbegbe Abule-Ẹgba, nipinlẹ Eko, ko too di pe wọn mu un ni eapọọtu. Bakan naa lọwọ ti tẹ awọn mi-in lara awọn ọmọọṣẹ awọn afunrasi ọdaran ọhun, awọn dukia kọọkan ti a gbagbọ pe tawọn afurasi ọhun ni ni NDLEA ti gbẹsẹ le bayii’’.

Alukoro ni gbogbo ọna lawọn maa gba lati fopin si bi awọn ọdaran se n ṣowo egboogi oloro laarin ilu. Tawọn si maa too foju gbogbo awọn tọwọ tẹ bale-ẹjọ.

Leave a Reply