NDLEA tileepo ti wọn n tọju egboogi oloro pamọ si pa

Adewale Adeoye

Awọn alaṣẹ ajọ to n gbogun ti gbigbe egboogi oloro lorileede wa, ‘ National Drug Law Enforcement Agency’ (NDLEA), ti ti fọwọ ofin ti ileepo kan ti wọn n pe ni ‘Oyoyo Filling Station,’ to n ta epo bẹntiroolu fawọn onimọto lojuna marosẹ Kaduna si Abuja pa patapata. Bakan naa ni wọn ti mu diẹ lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ elepo naa, ti wọn si ti n ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn. Ẹsun pe wọn n tọju egboogi oloro, igbo, sinu ọgba ileeṣẹ epo naa ni wọn fi  kan awọn ti ọwọ tẹ bayii. ALAROYE gbọ pe awọn kan ni wọn lọọ ṣofofo fawọn ajọ naa, ti wọn si lọ sibẹ lati foju wọn ri ohun to n ṣẹlẹ lagbegbe naa. Ṣe lẹnu ya wọn gidi nigba ti wọn ba ọpọlọpọ igbo mimu nibi ti wọn tọju rẹ si ninu ọgba ileeṣẹ epo naa.

Loju-ẹṣẹ ni wọn ti fọwọ ofin mu gbogbo awọn to n ṣiṣẹ nileeṣẹ ọhun lọ siluu Abuja lati lọọ fọrọ wa wọn lẹnu wo lori bi igbo ti wọn ba ninu ọgba naa ṣe jẹ gan-an.

Ọkan pataki lara ọga agba ajọ naa, ẹka ti ipinlẹ Kaduna, Ọgbeni Musa Bwalin, to sọrọ ọhun di mimọ fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, sọ pe gbogbo awọn tọwọ tẹ pata ni wọn ti wa ninu galagala awọn bayii, ti wọn si n ran awọn lọwọ ninu iwadii tawon n ṣe lọwọ.

O ni gbara tawọn ba ti pari iwadii tan lawọn maa foju gbogbo wọn pata bale-ẹjọ, ki wọn le fimu kata ofin.

Ni ipari ọrọ rẹ, o rọ awọn ọdọ ilu gbogbo pe ki wọn jinna rere si egboogi oloro to le ṣakoba fun igbesi aye wọn.

 

Leave a Reply