Ni bayii, wọn yoo maa fi ede Yoruba gba lansẹnsi mọto l’Amẹrika

Monisọla Saka

Oriire ni ọrọ naa jẹ fun gbogbo ọmọ Yoruba, paapaa ju lọ, awọn ti wọn fi orileede Amẹrika ṣe ibugbe pẹlu bi ijọba ipinlẹ Maryland, lorilẹ-ede ọhun ṣe gbe eto kan jade bayii. Eto naa ni pe wọn ti sọ ede Yoruba di ọkan lara awọn ede awọn alejo ti awọn to ba fẹẹ gba lansẹnsi mọto yoo fi maa ṣedanwo lati fi gba iwe naa, iforukọsilẹ mọto, ati eyi ti wọn yoo fi maa kawe fun igbaradi idanwo lati gba lansẹnsi naa.

Niluu Maryland yii, dandan ni ki eeyan gba iwe pe oun ẹfẹ maa kọ mọto tabi pe mọto wiwa ko i ti i dan mọran lọwọ oun, ko too di pe yoo gba iwe mo mọ ọn wa (driver’s license). Ede Yoruba si jẹ ọkan lara ede mẹsan-an ti wọn ṣẹṣẹ fi kun ede ti wọn fi n ṣeto idanwo fawọn to ba fẹẹ gbawe, pe ojulowo diraifa lawọn.

Wọn ni awọn fi ede Yoruba kun un nitori akọsilẹ latọdọ awọn eleto ikaniyan ilu naa to fidi ẹ mulẹ pe ede Yoruba jẹ ọkan lara awọn ede ajoji ti ki i ṣe ti Gẹẹsi to jẹ tawọn oniluu, ti wọn n sọ lagbegbe ibẹ.

 

Awọn ede to wa nilẹ tẹlẹ ki wọn too ṣe afikun tuntun ni ede Gẹẹsi ti i ṣe ede abinibi wọn, ede awọn ara Spain (Spanish), ede Faranse (French), Nepali, ede Korea, ede awọn ara Ṣaina atijọ (Chinese), ati Vietnamese.

Awọn ede ti wọn ṣẹṣẹ fi kun un ni Tagalog, Amharic, ti i ṣe ede awọn apa ilẹ Asia to sun mọ ilẹ Adulawọ, ede Larubawa (Arabic), Russian, Urdu, ede awọn ara India (Hindi), Farsi, Portuguese, irufẹ ede ti wọn fi n ba awọn odi sọrọ nilẹ Amẹrika (American Sign Language) ati ede Yoruba.

Ni bayii, wọn ni latinu oṣu Kẹsan-an, ọdun yii lọ, awọn olugbe Maryland, lorilẹ-ede Amẹrika, yoo ni anfaani lati maa ṣedanwo ti wọn fi n gbawe ọkọ lede Yoruba.

Ikede yii waye gẹgẹ bii ọkan lara eto idagbasoke agbegbe Maryland lati fi han pe itẹsiwaju n ba awọn, paapaa ju lọ ni gbogbo ọna ati nipa oriṣiiriṣii awọn ẹya agbaye to n gbe nibẹ.

Ẹka ileeṣẹ ipinlẹ Maryland to n ri si eto irinna ati awọn ti wọn n ṣeto iwe mọto ni awọn ṣeto irọrun ọhun, lati mu ki tolori tẹlẹmu le ni anfaani si gbogbo nnkan ti wọn ba nilo lai fi ti ẹya ṣe. O ni eyi waye latari awọn alakalẹ eto Gomina ilẹ Maryland, Gomina Wes Moore, to n fẹ igbaye-gbadun fun awọn eeyan Maryland.

 

Leave a Reply