Ni Kano, afaimọ ki Ganduje ma dojuti Tinubu

Adewumi Adegoke

Awọn esi idibo to n wọle lati ipinlẹ Kano ko fọkan awọn ololufẹ APC gbogbo balẹ rara o, bẹẹ ni ko fọkan awọn alatilẹyin Aṣiwaju Bọla Tinubu to n dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ naa paapaa balẹ, nitori ohun to n ṣẹlẹ nibẹ ko daa. APC ko ma ribo gidi mu nibẹ, awọn NNPP, ẹgbẹ oṣelu Rabiu Kwankwaso lo n ko gbogbo ibo ti wọn di, ẹgbẹ naa lo n ṣaaju awọn to ku gbogbo.

Ọkan ninu awọn ipinlẹ ti Aṣiwaju Tinubu ti gbojule pe yoo jẹ toun ni Kano, nitori Abdullahi Ganduje ti i ṣe Gomina ni ipinlẹ naa ko fi bo rara pe nile ni, loko ni, ti Tinubu loun n ṣe. Ko si ibi ti Tinubu n lọ ti ki i  ba a debẹ, ko si si eto kan ti APC yoo gbe kalẹ fun ondupo aarẹ naa ti ko ni i jẹ oun ni yoo ṣaaju nibẹ, ti yoo si maa sọ fun gbogbo eeyan pe ti Aṣiwaju ni ki wọn ṣe. Ni ipinlẹ rẹ ẹwẹ, ko si igberiko kan ti Ganduje ko de ni Kano yii, to n polowo Tinubu kaakiri.

Ṣugbọn nigba ti esi idibo bẹrẹ si i jade yii, ni origun mẹrẹẹrin ipinlẹ naa, nibi yoowu ti esi naa ba ti jade wa, ẹgbẹ Kwankwaso yii lo n bori gbogbo wọn. Nigba ti ọrọ naa yoo tilẹ foju han gbangba, ọmọ bibi inu gomina naa funra rẹ, iyẹn Abba Ganduje, naa dupo lati lọ si ileegbimọ aṣoju-ṣofin lati adugbo Dawakin-Tofa, ṣugbọn anajati ni Tijani Jobe ti ẹgbe NNPP yii na an, ti wọn si fi idi rẹ kalẹ pe ko le lọ sibi kan , ko lọọ jokoo nile baba rẹ.

Ohun to n mu ibẹru wa ninu awọn esi idibo to n jade ni Kano yii ni pe, Kanio ni wọn kọ orukọ rẹ sinu iwe ofin Naijiria pe ero pọ si ju lọ, ẹgbẹ oṣelu yoowu to ba si n du ipo aarẹ maa n lakaka lati mu Kano mọ ọn ni, nitori bi oloṣelu kan ba ti mu Kano, to si mu Eko, iṣoro rẹ din ku daadaa ni. Ohun ti Tinubu si gboju le ree, idi si niyi to fi n ṣe gbogbo atilẹyin fun wọn ni Kano, to si fi ọpọlọpọ owo ran ijọba ibẹ lọwọ. Ṣugbọn nigba ti nnkan waa daru mọ Ganduje funra ẹ lọwọ yii, afaimọ ko ma dojuti Tinubu o.

Leave a Reply