Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ija buruku kan waye lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, n’Ilogbo, nijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta. Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn n fi agba han ara wọn, wọn daamu araadugbo, wọn si ṣe ọkunrin ati obinrin kan lesẹ rẹpẹtẹ. Nibi ija naa lawọn ọlọpaa ti ko awọn gende meji yii, Jamiu Ọkanlawọn; ẹni ogun ọdun, ati Oluwaṣeun Owoẹyẹ; ẹni ọgbọn ọdun.
Agbegbe kan ti wọn n pe ni Orelope, n’Ilogbo, ni rogbodiyan ọhun ti waye, Alukoro ọlọpaa Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, si fidi ẹ mulẹ pe niṣe ni wọn fi aye ni awọn olugbe agbegbe naa lara, ti wọn ko le jade nitori awọn ẹlẹgbẹ okunkun to n gbode kan.
Nigba ti olobo ta DPO teṣan ọlọpaa Onipaanu, l’Ọta, oun atawọn ikọ rẹ lọ sibi ija naa lati pẹtu si i. Ibẹ ni wọn ti ri i pe wọn ti ṣe obinrin kan to n jẹ Mọdinat Lawal ati ọkunrin kan to n jẹ Ọpẹ Saheed leṣe gidi.
Bawọn arijagba naa ṣe ri awọn agbofinro ni wọn sa lọ, ṣugbọn Jamiu ati Oluwaṣeun yii ko ribi sa si, awọn ọlọpaa si mu wọn lẹsẹkẹsẹ, o di teṣan.
Ibọn ilewọ ibilẹ kan, ọta ibọn mẹta ti wọn ko ti i yin, àkọ̀ ọ̀bẹ kan (ibi ti wọn maa n fi ọbẹ si) ati awọn oogun oriṣiiriṣii lawọn ọlọpaa ba lọwọ awọn meji yii.
Bi wọn ti ko awọn ti wọn ṣe leṣe lọ sọsibitu lawọn ọlọpaa ko Jamiu ati Oluwaṣeun naa lọ sẹka ti wọn yoo ti fi ibeere ṣe aye wọn leṣe, ki wọn too ko wọn lọ si kootu fun igbẹjọ.