Eeyan mẹta ku nibi ijamba ọkọ BRT ati ọkada

Monisọla Saka

Awọn ọdọmọkunrin meji ati ọlọkada to gbe wọn ti ki aye pe o digbooṣe, lẹyin ti bọọsi bọginni akero ipinlẹ Eko, BRT gba wọn danu lagbegbe Alakija, nipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe fidi ẹ mulẹ, nibi ere bọọlu alafẹsagba ti wọn ti kopa ni awọn ọkunrin mejeeji naa ti kuro lagbegbe Navy Town, ijọba ibilẹ Ọjọ, nipinlẹ Eko.

Ọkada ti yoo gbe wọn dele, nitori sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ọkọ ni wọn ni awọn mejeeji gun. Amọ to jẹ pe ọkọ BRT to n lọ si agbegbe Okokomaiko, nijọba ibilẹ Ọjọ, nipinlẹ Eko, ni wọn lọọ lari mọ.

Bo si tilẹ jẹ pe ṣaaju akoko yii ni ijọba ipinlẹ Eko ti fofin de gigun ọkada lawọn oju ọna marosẹ. Bẹẹ ni wọn tun ṣe e leewọ fawọn ọlọkada lati ma ṣe gba oju ọna BRT to lọ lati Mile 2 si Okokomaiko, paapaa ju lọ pẹlu bi ọkọ BRT ṣe ti bẹrẹ iṣẹ ni agbegbe ibẹ naa, sibẹ wọn ko yee gba a.

Ninu fidio ibudo iṣẹlẹ naa ti wọn gbe sori ayelujara Twitter, niṣe ni ọkada ati ẹsẹ ẹni to wa a ha mọ imu ọkọ naa. Awọn meji to gbe si na kalẹ gbalaja, balabala ni gbogbo ilẹ ibẹ kun fun ẹjẹ.

Nigba tawọn ọdọ agbegbe naa jade lati ṣugbaa awọn to ni ijamba ni wọn ri i pe awọn mẹtẹẹta ti gbẹmii mi.

Nitori bẹẹ ni wọn ṣe fa ibinu yọ, ti wọn lawọn maa dana sun ọkọ BRT naa.

Bi ki i baa ṣe ọpẹlọpẹ ọga ọlọpaa tẹṣan agbofinro Festac, Balogun Gboyega, to tete de sibẹ ni, awọn bọisi ọhun ko ba ti ba nnkan jẹ, bẹẹ ni wọn ko ba ti tun fẹmi ọkunrin to wa ọkọ naa ṣofo.

Ẹni kan tọrọ ṣoju ẹ, to ba iwe iroyin Vanguard sọrọ, ṣalaye pe awọn ọlọpaa ni wọn gba awakọ naa silẹ lọwọ awọn eeyan tinu n bi, ti wọn si fẹẹ fibinu pa a danu.

Bakan naa ni wọn ni mọlẹbi ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa kan ti waa gbe eeyan wọn lọ, nigba ti awọn agbofinro palẹ awọn meji yooku lọ si teṣan wọn.

Awọn ọlọpaa yii naa ni wọn ni wọn wọ ọkọ BRT ọhun, ati ẹni to wa a lọ si agọ wọn.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, SP Benjamin Hundeyin, ti i ṣe Alukooro ọlọpaa Eko, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ku ogun iṣẹju ni iṣẹlẹ naa waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹwaa, ọdun yii.

O ni ọkọ BRT Mercedes, pẹlu nọmba iforukọsilẹ BRI 043, ti i ṣe ti ijọba ipinlẹ Eko, eyi ti ọkunrin kan ti wọn n pe ni Olubor Oluwaṣẹgun wa, n lọ si agbegbe Iyana Iba, nirọlẹ ọjọ naa ni, amọ to jẹ pe Alakija ni wọn de toun ati ọkada fi fori sọ ara wọn.

“Oju ọna ti ki i ṣe tiẹ ni ọkada to ko ero meji naa gba. Awọn ero mejeeji ti ọkada naa ko ni Waidi Kadiri Momoh, ẹni ọdun mẹtalelogun (23), ati Enegide Azuka, ẹni ogun ọdun (20). Bakan naa ni wọn ni ọrọ naa kan ọkunrin kan to n jẹ Divine Omosowo, ṣugbọn ti Ọlọrun ko jẹ ki tiẹ ja si iku.

“Awọn eeyan mẹtẹẹta ti wọn gun ọkada ni wọn ku loju-ẹsẹ, amọ ti wọn ti gbe Omosowo, toun fara pa ni tiẹ lọ sile iwosan fun itọju to peye”.

O ni nigba ti ọkan lara awọn mọlẹbi ọkan ninu awọn mẹta to doloogbe ti waa gbe ọmọ wọn, wọn ti gbe oku awọn meji yooku lọ sile igbokuu-pamọsi Mainland General Hospital Mortuary, Yaba, nipinlẹ Eko.

Leave a Reply