Nibi tawọn ajinigbe yii sa pamọ si lọwọ ọlọpaa ti tẹ wọn l’Ayetoro

Gbenga Amos, Abẹokuta
Awọn ogbologboo ajinigbe mẹsan-an ti wọn n yọ awọn eeyan Abẹokuta si Ayetoro lẹnu nipinlẹ Ogun ti ko sakolo awọn ọlọpaa, ọpẹlọpẹ awọn ọdẹ, awọn ẹṣọ alaabo ‘So Safe’, awọn OPC, figilante atawọn ikọ Amọtẹkun to fọwọ sowọ pọ, ti wọn fi ri awọn amookunṣikan ẹda naa mu ṣikun ni ibuba wọn.
Ibi kan ti wọn n pe ni Abule Ọba, lọna ilu Ayetoro, nitosi Abẹokuta, ni wọn ti lọọ ka awọn afurasi naa mọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin yii.
Mẹsan-an ni wọn, orukọ wọn gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe to o ninu atẹjade to fi ṣọwọ s’ALAROYE ni Hammed Taiwo, Kẹhinde Jimọh, Umar Sanda, Ali Morandu, Usman Abubakar, Usman Mohammed, Umaru Ahmadu ati Umaru Mọmọdu.
Ọwọ palaba wọn segi lẹyin ti awọn ọlọpaa ti ẹka
Sabo/Ilupeju ri i gbọ pe wọn ri Hammed Taiwo ati Kẹhinde Jimoh ti wọn jẹ ọlọkada to n jiṣẹ kiri fawọn kọlọransi ẹda yii, tawọn naa si tun jẹ ara wọn, lagbegbe Rounder, nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta.
Oju-esẹ ni ọga ọlọpaa ẹka Sabo/Ilupeju, SP Mustapha Ọpawọye, ti sare ko awọn ọlọpaa jọ pe ki wọn maa lọ si agbegbe ọhun, nibẹ ni ọwọ ti tẹ Hammed Taiwo ati Kehinde Jimoh.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ṣe fun wọn ni wọn ti jẹwọ pe ara awọn ọdaran yii lawọn naa, ṣugbọn iṣẹ tawọn ni lati maa jiṣẹ kaakiri fun wọn, kawọn si tun maa ba wọn ṣọ ayika, nitori ki awọn agbofinro ma baa kọ lu wọn lojiji.
Ijẹwọ wọn yii lo mu ki ileeṣẹ ọlọpaa mọ ibuba awọn ajinigbe naa, ibẹ ni wọn ti maa n pade lẹyin ti wọn ba ti gbowo lọwọ awọn ti wọn ji gbe tan. Ọga ọlọpaa ṣeto pẹlu awọn ẹṣọ alaabo yooku, ni wọn ba ya bo ibuba awọn ajinigbe yii, ti wọn si ko wọn.
Iwadii ti wọn ṣe ṣaaju akoko yii jẹ ko di mimọ pe awọn ikọ ọdaran yii ni wọn n da agbegbe oju ọna Abẹokuta si Ayetoro laamu lẹnu ọjọ meta yii. Koda pupọ ninu awọn ti wọn ti ṣagbako awọn ẹni ibi yii ni wọn ni awọn da wọn mọ, ati pe awọn ni wọn ji awọn gbe.
Ni bayii, Kọmiṣanna ọlọpaa, Lanre Bankọle, to fi idunnu rẹ han lori ọgbọn inu tawọn eeyan rẹ ta ti wọn fi ri awọn ọdaran naa mu, o si ti paṣẹ pe ki wọn taari wọn lọ si abala awọn to gbogun ti iwa ijinigbe lẹka ileeṣẹ ọlọpaa, fun iwadii to lọọrin.

Leave a Reply