Faith Adebọla, Eko
Awọn gende mẹta kan to fẹẹ gbe egboogi olori kọja papakọ ofurufun Muritala Mohammed to wa n’Ikẹja, l’Ekoo, ti ha sọwọ awọn agbofinro, awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti gbigbe, lilo ati ṣiṣe okoowo egboogi oloro nilẹ wa, NDLEA, lo mu wọn.
Meji ninu awọn afurasi ọdaran naa, Emeka Jeremiah Azubuike, ati Uchenna Okeke, ni wọn fẹsun kan pe wọn fẹẹ ko awọn egboogi wọle pẹlu baalu Ethiopia kan to n gbe wọn bọ lati orileede Brazil, igba ti wọn n yẹ ẹru wọn wo laṣiiri tu pe wọn lẹbọ lẹru.
Ẹni kẹta, Musa Abdul, ni wọn loun fẹẹ gbe egboogi ti wọn pe ni kokeeni kọja si orileede India, wọn ni diẹ lo ku ko wọ baalu pẹlu ẹru ofin to wa lara ẹ.
Kọmanda ajọ NDLEA to wa ni papakọ ofurufu naa, Ọgbẹni Garba Adamu, to ṣalaye fawọn oniroyin nipa iṣẹlẹ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, sọ pe laarin ọjọ kẹjọ si ikẹwaa, oṣu yii, lọwọ ba awọn afurasi naa, tawọn si bẹrẹ iwadii lori wọn.
Adamu ni aropọ egboogi ti wọn ka mọ wọn lọwọ wọ kilogiraamu mejidinlogoje (137.8 kg).
O sọ pe niṣẹ lawọn afurasi naa pọn kinni ọhun saarin awọn aṣọ kampala, wọn tọju awọn mi-in saarin ọṣẹ ifọrun, iyẹn rilaasa (hair relaxer) tawọn obinrin n lo, wọn si fi beba kabọn ati girisi pa a lara.
Nigba ti wọn bi wọn leere, awọn afurasi naa jẹwọ pe ero awọn ni pe bawọn ṣe tọju ọja ofin ọhun ko ni i jẹ ki ẹrọ igbalode to n ṣayẹwo ẹru le gbooorun awọn egboogi naa, ṣugbọn ibi ti wọn foju si, ọna ko gba’bẹ.
Ahmadu ni awọn afurasi naa ti wa lẹnu ọna ile-ẹjọ, tori tawọn ba ti pari iṣẹ iwadii, awọn ati ẹsibiiti ẹru ofin ti wọn ko yoo fara han niwaju adajọ laipẹ.