Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lalẹ, ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ ọjọ kejila, oṣu kọkanla, lawọn ọkunrin mẹta yii; Bamidele Oluwashina, Adebọwale Kẹhinde ati Oluwaṣẹgun Abayọmi, digunjale laduugbo kan ti wọn n pe ni Iju-Ọta, nipinlẹ Ogun, ti wọn n fi nnkan ija gba dukia awọn eeyan lọwọ wọn.
Ibudokọ Iju-Love ati Tipper Garage, gan-an ni wọn ti n pitu ọhun gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi ṣe wi.
O ni nibi ti wọn ti ko jinni-jinni ba awọn eeyan lẹni kan ti pe teṣan ọlọpaa Onipaanu, l’Ọta, pe idigunjale n lọ lọwọ ni Iju-Ọta o.
Bawọn ọlọpaa ṣe debẹ ni wọn ṣina ibọn bolẹ lati dẹruba awọn ole yii, ṣugbọn niṣe lawọn naa bẹrẹ si i da tiwọn pada, wọn ko sa rara.
Nigba ti ikọ adigunjale naa ri i pe ibọn ọlọpaa le ju eyi tawọn n lo lọ ni wọn dọgbọn sa, ṣugbọn ọwọ ba ọkan ninu wọn.
Kia lawọn agbofinro ti gba gbogbo agbegbe naa kan, pẹlu iranlọwọ awọn eeyan ibẹ, wọn ri awọn meji yooku mu, nigba ti wọn n dọgbọn sa lọ ninu kẹkẹ Maruwa kan.
Ṣaaju lawọn ole yii ti bu Tosin Ajayi ladaa lori, niṣe lawọn ọlọpaa sare gbe e lọ si ọsibitu fun itọju.
Ibọn ilewọ ibilẹ kan ati ọta ibọn meji ti wọn ko ti i yin lawọn ọlọpaa ba lọwọ ikọ adigunjale yii; wọn si ti taari wọn sẹka itọpinpin labẹnu, gẹgẹ bi CP Edward Ajogun ṣe paṣẹ.