Faith Adebọla
Bo ba jẹ ori tẹlifiṣan lawọn tọkọ-tiyawo yii ti n fẹsun kan ara wọn ni, niṣe leeyan iba kọkọ ro pe awada kẹrikẹri ni wọn n ṣe, tabi pe ipa ti wọn ni ki wọn ṣe ninu fiimu ni, amọ wọn ki i ṣe adẹrin-in poṣonu rara, ohun to si jẹ ẹdun ọkan wọn ni wọn n sọ jade pẹlu bi iyaale ile kan, Oluwatoyin Falade, ṣe fẹsun kan ọkọ rẹ, Ọgbẹni Ṣẹgun Falade, nile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa l’Orile-Agege, nipinlẹ Eko, pe agbere ṣiṣe ti jaraaba ọkọ oun, kinni naa ti waa kọja gejia debii pe b’oun ṣe n wo o yii, afaimọ ni ko ni i ki awọn ọmọbinrin toun bi fun un mọlẹ lọjọ kan, ti yoo si fipa ba wọn sun, tori ẹ loun ṣe rawọ ẹbẹ si kootu naa pe ibi toun ba irinajo igbeyawo ọlọdun mọkanla oun atọkọ oun de yii loun ti fẹẹ duro ni toun, oun o ṣe mọ, ki kaluku maa lọ nilọ ẹ.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un yii, ni igbẹjọ naa bẹrẹ lori ẹsun ti Toyin fi kan ọkọ rẹ ọhun.
Toyin yii lo wọ ọkọ rẹ lọ sile-ẹjọ kọkọ-kọkọ naa, to si beere pe ki wọn tu igbeyawo awọn ka latari ẹsun agbere to fi kan baale rẹ.
Ninu alaye rẹ niwaju adajọ, o lọmọ meji loun ti bi fun ọkunrin yii, obinrin si lawọn mejeeji, ọkan jẹ ọmọọdun mọkanla, nigba tọjọ-ori ekeji ko ju ọdun mẹjọ lọ.
Toyin ni: “Oluwa mi, oniṣina paraku ni ẹni ti mo fi ṣe ọkọ yii. oloju ko-mu-o-lọ patapata gbaa ni, ko ṣaa ti ma foju kan iro ati sikẹẹti obinrin ni, o digba to ba dedii ohun ti wọn ro’ṣọ le lori naa.
“Ọmọ meji ni mo ti bi ki n too fẹ ẹ, ọmọọdun mejidinlogun ati mẹẹẹdogun ni wọn. Gbogbo wa jọ n gbe ni, amọ ni bayii, ọkan mi o lelẹ mọ, nigba ti mo ri i bi agbere ti ṣe wọ ọkọ mi lẹwu to. Niṣe lo n paarọ awọn ale ẹ bii ẹni paarọ ẹwu, ko sobinrin ti ko le kọnu iṣekuṣe si, ko tiẹ ni ọwọ eleepinni femi iyawo to fẹ sile rara.
“O ti su mi patapata, tori bo ṣe wa yii, ko le yipada, gbogbo aye ti ba a sọrọ titi, a gun ata lodo, a lọ ata lọlọ lọrọ, sibẹ iwa ata o yipada. Agbere ẹ ko si jẹ ko roju gbọ bukaata lori awọn ọmọ debi ti yoo tọju mi. Emi nikan ni mo n fori fa gbogbo atijẹ atimu ninu ile, ti mi o ba lọkọ paapaa, o san ju aku-u-ni ọkọ lọ.
“Oluwa mi, mo rọ yin pe kẹ ẹ tu wa ka, mi o ṣe mọ o, tori tẹ ẹ ba tu wa ka, ma a wulẹ palẹ ẹru mi mọ, emi atawọn ọmọ mi aa sa lọ si jinna jinna ni o.”
Nigba ti wọn beere bọrọ naa ṣe jẹ lọwọ ọkọ ẹ, Ṣẹgun, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta, o ni ko sirọ ninu ọrọ iyawo oun, o ni ki wọn ṣaa ba oun bẹ ẹ ko ma kọ oun silẹ ni.
Ṣẹgun jẹwọ niwaju adajọ pe: “Mi o ni i purọ, loootọ ni mo maa n ko obinrin, mo si maa n gbe oriṣiiriṣii obinrin wale paapaa. Ṣugbọn mo ti ṣetan lati yipada, mo ti n bẹ ẹ pe ko fori jin mi, ma a jawọ, ẹ ṣaa ba mi bẹ ẹ.”
Wọn tun beere lọwọ ẹ pe ki lo ri si ti aitọju idile ẹ, niṣe ni baale ile yii sọrọ naa di awada, o ni: “Haa, Oluwa mi, ẹyin naa ẹ woju iyawo mi, ẹ o ri i bo ṣe n dan loju, tawọ ẹ jọlọ ni, ṣe ẹni tẹyin naa ri yii jọ ẹni t’ọkọ n fiya jẹ. Aipẹ yii ni mo ṣẹṣẹ ra foonu ọwọ ẹ yii fun un, emi si ni mo n sanwo ileewe awọn ọmọ wa.”
Ṣẹgun ni oun o fara mọ ẹbẹ iyawo oun, o ni kile-ẹjọ ma ṣe tu awọn ka, o loun maa ṣatunṣe to ba yẹ ti wọn ba le foun laaye lẹẹkan si i.
Lopin atotonu wọn, Adajọ Adewale Adegoke to jẹ alaga kootu naa sun igbẹjọ si ọgbọnjọ, oṣu Karun-un yii.