Stephen Ajagbe, Ilorin
Afurasi ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, Yusuf Abdullahi, lọwọ ileeṣẹ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, tẹ lagbegbe Gbogbo Giwa, niluu Kaiama, nipinlẹ Kwara, lasiko to n ka mọ ọmọ ọdun mọkanla kan.
ALAROYE gbọ pe fiimu ilẹ India kan to wa lori foonu rẹ lo fi foju ọmọ naa mọra, biyẹn ṣe n jokoo ti i to n wo fiimu naa ni Abdullahi bẹrẹ si ni fọwọ pa a lara to si n gbiyanju lati ba a laṣepọ ko too di pe ilẹ mọ ba a.
Alukoro ileeṣẹ NSCDC, Babawale Zaid Afọlabi, ṣalaye pe ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ owurọ.
O ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ awọn to wa ni Kaiama lo ri ọkunrin naa nibi to ti n wọ ọmọ naa mọra to si n ba a ṣere ifẹ.
Nigba ti wọn beere lọwọ ẹ ohun to fi wu iru iwa naa, ohun to sọ ni pe iyawo oun ṣẹṣẹ bimọ ni, oun ko le ba a ṣere ifẹ bayii.
Afọlabi fi kun un pe alajọgbe ni Abdullahi, iyawo rẹ ati ọmọ mẹta pẹlu awọn obi ọmọbinrin naa.
O ni ohun ti Abdullahi sọ ni pe, ọmọbinrin naa lo waa ji oun nibi toun ti n sun, bo si ṣe de lo ni koun mu foonu oun wa, oun si gbe fiimu India kan sita koun too gbe e le e lọwọ.
Abdullahi ni oun kan n fọwọ pa a lara ni, oun ko tii gbiyanju lati ba a laṣepọ ko too di pe wọn ri oun.
Afọlabi ni awọn ti gbe ọmọde naa lọ silewosan fun ayẹwo lati wadii boya loootọ l’ọkunrin naa ti wọle si i lara tabi bẹẹ kọ.
O ni lẹyin iwadii, awọn yoo wọ ọ lọ sile-ẹjọ.