Gbenga Amos, Abẹokuta
Jẹbẹtẹ ti gbọmọ le ojiṣẹ Oluwa ẹni aadọta ọdun kan, Pasitọ Isaac Akinbọla, lọwọ. Ibi toun atawọn ale rẹ meji to bẹ lọwẹ lati lu iyawo ẹ to n tọmọ lọwọ ni Ọbadiah Akinbọla, ọmọ oṣu mẹjọ tobinrin naa n tọ lọwọ ti ja bọ, to si ku patapata.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, fidi ẹ mulẹ f’ALAROYE pe iṣẹlẹ naa waye lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta to kọja yii, lagbegbe Mamu Ijẹbu, nijọba ibilẹ Ariwa Ijẹbu, nipinlẹ Ogun.
Iyawo pasitọ yii, Abilekọ Dasọla Akinbọla, lo lọọ fiṣẹlẹ yii to awọn ọlọpaa leti ni teṣan wọn ni Awa Ijẹbu, pe ọkọ oun ti ko awọn ale ẹ waa ka oun mọle, wọn si ti pa oun lọmọ nibi ti wọn ti n lu oun bii ẹni lu ẹgusi baara.
Alaye tobinrin naa ṣe fawọn ọlọpaa ni pe aawọ ti wa nilẹ tẹlẹ laarin oun ati ọkọ oun, aawọ naa ko si ṣẹyin ẹsun toun fi kan an pe ko duro ti adehun igbeyawo awọn mọ, o loun hu u gbọ pe o n yan awọn obinrin ṣọọṣi rẹ lale, o ni Esther Olowolayemọ, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, ati Oluwakẹmi Oṣinbajo, ẹni ọgbọn ọdun, wa lara awọn ale rẹ.
Gbọnmi-si-i-omi-o-to ọrọ yii lo mu koun ṣi rọra yẹra fun un diẹ na, toun si fi n da gbe pẹlu ọmọ ikoko toun n tọ lọwọ.
Ṣugbọn lọjọ iṣẹlẹ yii, Pasitọ naa ko awọn obinrin mejeeji ọhun, Oluwakẹmi ati Esther, waa ka oun mọle, bi wọn si ṣe de lọkọ oun ni ki wọn bẹrẹ si i ṣe oun bọṣẹ ṣe n ṣe oju, o lawọn mẹtẹẹta ni wọn dawọ bo oun, ti wọn lu oun gidi.
Obinrin naa ni ibi toun ti n dura oun, toun n du ọmọ ọwọ oun, pẹlu bi wọn o ṣe jẹ koun raaye sa jade, ibẹ lọmọ ẹjẹ ọrun naa ti jabọ lojiji, lọrọ ba di ran-n-to.
Ṣa, nigba tawọn ọlọpaa debi iṣẹlẹ yii, wọn mu awọn afurasi ọdaran mẹtẹẹta, iyẹn Pasitọ atawọn ale ẹ, gẹgẹ bii aṣẹ ti DPO ẹka Awa Ijẹbu, CSP Joshua Adewalẹyinmi, pa, wọn si ṣaajo ọmọ naa ati iya rẹ, wọn mu wọn dele-iwosan Mamu Ijẹbu. Lẹyin itọju diẹ, awọn oṣiṣẹ ileewosan naa ni ki wọn maa lọ sileewosan Blessed, to wa ni Orù Ijẹbu, ibẹ layẹwo ti fihan pe wọn ti ṣe ọmọ naa leṣe gidi, o si ti lọgbẹ inu, latari bo ṣe ja bọ lasiko ija ọhun. Ọjọ keji lọmọ naa ṣalaisi, ni wọn ba gbe oku rẹ lọ si mọṣuari Ọsibitu Jẹnẹra, n’Ijẹbu-Igbo.
Ẹka ti wọn ti n tọpinpin iwa ọdaran abẹle bii eyi ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ni ki wọn ko ọrọ wọn lọ. Ibẹ ni wọn maa gba dewaju adajọ laipẹ.