Nibi ti Bọde ti fẹẹ ji ọmọ ọlọmọ gbe ni wọn ti mu un l’Okitipupa Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Afurasi ọdaran kan, Bọde Agbedun, ti n jẹjọ lọwọ nile-ẹjọ Majisireeti kan to wa lagbegbe NEPA, niluu Akurẹ, lori ẹsun idigunjale ati ijinigbe ti wọn fi kan an.

Bọde ti ko ti i pẹ rara to ṣẹṣẹ de lati ọgba ẹwọn ni wọn lo gbimọ-pọ pẹlu awọn ẹgbẹ rẹ kan tawọn agbofinro ṣi n wa lati lọọ fọ ile ẹnikan ti wọn porukọ rẹ ni Ilesanmi Goodluck, nibi ti wọn ti digun ja ọkunrin naa lole, ti wọn si tun gbiyanju ati ji ọkan ninu awọn ọmọ rẹ gbe.

Iṣẹlẹ yii ni wọn lo waye ni nnkan bii aago meji oru ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kọkanla yii, niluu Ìgòdàn Lísà, eyi to wa nijọba ibilẹ Okitipupa.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla yii, lawọn ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo wọ afurasi naa lọ sile-ẹjọ fun ẹsun ijinigbe, idigunjale, ile fifọ ati biba awọn nnkan ija oloro nikaawọ rẹ.

Awọn ẹsun marun-un ti wọn fi kan an ni agbẹjọro ijọba, Amofin N. O. Nwafor, ni wọn ta ko abala kẹfa ati ikarun-un ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2010, eyi to lodi si iwa ijinigbe, abala kin-in-ni, ẹkẹfa ati irinwo le mọkanla ninu akanṣe iwe ofin Naijiria ọdun 2004, ati abala irinwo le mejila ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Agbefọba ọhun ninu ẹbẹ rẹ rọ ile-ẹjọ lati fi olujẹjọ naa pamọ sọgba ẹwọn Olokuta, titi ti imọran yoo fi wa lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Damilọla Ṣekoni, gba ẹbẹ Amofin Nwafor wọle pẹlu bo ṣe ni ki ọkunrin naa ṣi lọọ maa gbatẹgun ninu ọgba ẹwọn Olokuta, titi di ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024.

 

 

 

 

 

Leave a Reply