Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Ara ọmọ to ta iya kan ti wọn n pe ni Iya Maria, lagbegbe Ijohun, ni Yewa, lo ran an sọrun lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii. Awọn ajinigbe mẹrin lo fẹẹ gbe Maria, ẹni ọgbọn ọdun ati ọmọ ẹ to pọn sẹyin lọ. Bi Iya Maria ṣe bẹrẹ si i pe awọn eeyan pe ki wọn waa ran oun lọwọ ni awọn agbebọn naa yinbọn fun un, to si ku lẹsẹkẹsẹ.
Awọn fijilante ti wọn n pe ni So-Safe, ẹka ti Ketu, ni iṣẹlẹ naa ṣoju wọn. Aago mejila oru ku iṣẹju mẹẹẹdogun ni wọn ni awọn ajinigbe mẹrin naa de lori ọkada Bajaj meji, bi wọn ṣe sọkalẹ ni wọn wọle awọn Iya Maria, ti wọn si gbe Maria ati ọmọ rẹ tiyẹn n tọ lọwọ lọ.
Eyi ni Iya Maria ri to fi fariwo bọnu, n lawọn ajinigbe naa ba fibọn ranṣẹ latẹyin si iya yii, obinrin naa si ku lẹsẹkẹsẹ.
Ọpẹlọpẹ ikọ So-Safe ti wọn gba ya awọn ajinigbe naa ni wọn gba Maria ati ọmọ rẹ kalẹ lọwọ wọn.
Mẹta ninu awọn ajinigbe yii sa lọ gẹgẹ bi Alukoro So-Safe, Mọruf Yusuf, ṣe sọ. O ni ṣugbọn ọwọ ba ọkan ninu wọn torukọ ẹ n jẹ Jimọh Fayẹmi.
Ibọn ṣakabula mẹta ati ọkada meji ti wọn gbe wa ni awọn So-Safe sọ pe awọn ri gba lọwọ Jimọh tọwọ ba naa.
Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eegua, ni wọn lawọn fa Jimọh ati awọn ohun tawọn gba lọwọ ẹ naa le lọwọ fun itẹsiwaju iwadii ati gbigbe e lọ si kootu.
Bẹẹ ni wọn ni iṣẹ n lọ lori ati ri awọn mẹta yooku to sa lọ ninu awọn ajinigbe naa mu.