Ajalu nla ṣẹlẹ lakata awọn Ogboni ilẹ Yoruba lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nigba ti ijamba ọkọ gbẹmi olori wọn, Dokita Adetoyeṣe Abdul Ọlakiṣan, Oluaye Ọba Ogboni Agbaye, to tun jẹ Awiṣẹ Iwaṣẹ ti ilẹ Yoruba.
Gẹgẹ bi Alaroye ṣe gbọ, awọn ajinigbe tẹnikẹni ko ti i mọ boya Yoruba ni wọn tabi Fulani ni wọn ya wọ ile baba naa ni Imẹsi Ile, nipinlẹ Ọṣun, laarin oru ọjọ Aiku, Sannde, mọjumọọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti wọn si ji meji lara awọn iyawo baba naa gbe lọ.
Nigba ti ilẹ mọ ni baba yii gbe ọlọpaa kan to jẹ ọga wọn ni teṣan to wa ni Imẹsi Ile ati obinrin kan sinu ọkọ, ti wọn si n wa awọn ti wọn ji gbe naa kaakiri.
Nigba ti wọn wa wọn titi de ilu Ila, ni wọn ṣẹri pada lati lọọ tun ero pa, ṣugbọn bo ṣe ku diẹ ki wọn de Ẹdẹmọsi, ni nnkan bii aago meji ọsan, ni ọkọ wọn fori sọ igi kan lẹgbẹẹ ọna.
Ko seyii to de ọsibitu laarin awọn mẹtẹẹta ti ẹlẹmi-in fi gba a, a gbọ pe ijamba naa pọ pupọ debii pe loju-ẹsẹ lawọn mẹtẹẹta ti wọn wa ninu mọto naa jade laye.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn ẹṣọ alaabo loriṣiiriṣii ti bọ sinu igbo agbegbe naa lati ṣawari awọn iyawo baba yii mejeeji ti wọn ji gbe.