Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ija agba kan to lagbara waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ ati Alora lagbegbe Ajegunlẹ, Ibogun, nipinlẹ Ogun, lọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii, nibẹ ni eeyan mẹsan-an ti wọn jẹ ọmọ Ẹyẹ ti bọ sọwọ ọlọpaa.
Awọn mẹsan-an ọhun ree gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi ṣe, pe wọn:
Sọdiq Ọlabisi, Oluwatosin Andrew, Ọladimeji Oyedele, Wasiu Raheem, Oyedokun Lekan,Yusuf Ajetunmọbi, Busari Taoreed, Bọlaji Rapheal ati Salami Tọheeb.
Alukoro ṣalaye pe ija naa le debii pe wọn ti da apa oriṣiiriṣii si aya ọmọ ẹgbẹ Alora kan yannayanna, iyẹn ti ṣeṣe silẹ buruku kawọn ọlọpaa too debẹ nigba ti olobo ta wọn.
Bawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ṣe ri ọlọpaa ni wọn ka a nilẹ, wọn n sa lọ. Ṣugbọn ọwọ ba awọn mẹsan-an yii ninu wọn, awọn mi-in ti wọn ti ṣeṣe si sa lọ pẹlu.
Ada kan, ọbẹ marun-un, aake meji, batiri foonu marun-un ati ẹgbẹrun mẹrin naira lawọn ọlọpaa ri gba lọwọ awọn ti wọn mu yii.
CP Edward Ajogun ti ni ki wọn wa awọn to sa lọ ri, ki wọn si ko awọn eyi tọwọ tẹ yii lọ sẹka to n gbọ iwa ọdaran nipinlẹ Ogun.