Nibi to ti n sare asapajude, danfo kan gbokiti, gbogbo ero inu ẹ lo fara pa

Adewale Adeoye

Ọsibitu ijọba to wa ni agbegbe Ile-Epo, ni Abule-Ẹgba, niluu Eko, ni wọn ko awọn eeyan meje to fara pa ninu ijamba mọto kan to waye lọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii, lagbegbe Super si Ile-Epo, niluu Eko, lọ fun itọju pajawiri.

Mọto danfo kan la gbọ pe o gbokiti latari ere asapajude ti ọkọ naa n sa, lojiji lo pade mọto Mazda alawọ buluu kan ti nọmba rẹ jẹ (AGF 991YC) ni dẹrẹba danfo naa ko ba mọ ohun ti yoo ṣe mọ.

Raba-raba pe ko ma lọọ kọ lu mọto ọhun, ti ko si tun fẹẹ kọ lu mọto ijọba (BTR), to n bọ lẹgbẹẹ keji lo ṣe kọ lu kọlufẹẹti to wa loju titi, loju-ẹsẹ ni mọto danfo ọhun ti gbokiti laimoye igba. Eyi lo fa a to fi jẹ pe gbogbo ero mejeeje to wa ninu mọto danfo naa lo fara pa gidi gan-an.

Iṣẹ gidi ni ajọ to n gbogun ti igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, LASTMA, ṣe lati pese aabo ati iranlọwọ fawọn to wa ninu mọto naa, awọn ni wọn n ṣakoso oju ọna titi ti wọn fi gbe aọn eeyan naa lọ sileewosan fun itoju.

Alukoro ajọ LASTMA nipinle Eko, Ọgbẹni Adebayọ Taofiq, ni ere asapajude ti mọto danfo ọhun n sa bọ lo fa iṣẹlẹ naa. Bakan naa lo rọ awọn dẹrẹba ọkọ akero gbogbo, paapaa awọn mọto danfo, pe ki wọn yee sare ju loju popo.

Bakan naa ni ọga agba ileeṣẹ LAMATA nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Bọlaji Ọrẹagba, rọ awọn awakọ mọto danfo pe ki wọn yee sare loju titi, ki wọn si ṣọra fun imukumu ti wọn ba n wa mọto lọwọ.

 

Leave a Reply