Nibi to ti n sare buruku, ọkọ akẹru wo pa alabaaru l’Ekoo

Monisọla Saka

Ọkunrin Mọla to n fi ọmọlanke titi ṣiṣẹ ṣe ti pada iku ojiji lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, lasiko ti kọntena ọkọ akẹru nla kan to ko awọn okuta wọywọyọ, wo lu u mọlẹ lagbegbe Dọpẹmu, nipinlẹ Eko, tọkunrin naa si padanu ẹmi rẹ sinu ẹ.

Adebayọ Taofiq, ti i ṣe agbẹnusọ ajọ to n ri si igboke-gbodo ọkọ nipinlẹ Eko( LASTMA), sọ pe loju-ẹsẹ lọkunrin Hausa naa gbẹmi-in mi.

ALAROYE gbọ pe ọkunrin awakọ tipa yii sọ ijanu ọkọ rẹ nu ni lasiko to n du ọna pẹlu tirela nla mi-in loju ọna marosẹ Eko si Abẹokuta ọhun.

Ere asaju yii ni wọn lo ṣokunfa bi ọkọ naa ṣe yawọ kuro loju titi lojiji, nigba ti yoo si wo lulẹ, oju ọna ti ọkọ bọginni BRT ipinlẹ Eko maa n gba lo ṣubu le, to si ṣe bẹẹ dabuu ọna to wọnu Dọpẹmu lọ.

Lọgan ti ijamba naa ti ṣẹlẹ ni awakọ tirela ọhun ti dawati, ṣugbọn pẹlu bo ṣe fẹsẹ fẹ ẹ naa, wọn lawọn oṣiṣẹ LASTMA ri iwe-ẹri awakọ (Driver’s license), to wa ninu ọkọ rẹ mu.

Lẹyin ti wọn palẹ mọto to ṣubu ati gbogbo ẹru inu ẹ mọ tan ni wọn ṣẹṣẹ ri ọkunrin Hausa ọlọmọlanke naa yọ jade.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede ni wọn ti sọ pe, “Lẹyin ta a ti ri i pe eeyan kan ti ha sabẹ mọto to wo lulẹ la ranṣẹ pe awọn ileeṣẹ to n ri si ọrọ pajawiri nipinlẹ Eko (LASEMA)  atawọn agbofinro lati teṣan wọn to wa ni Gowon Estate.

Bawọn LASEMA ṣe palẹ ọkọ to wo lulẹ kuro loju ọna BRT tan ni wọn yọ oku ọkunrin naa jade, ti wọn si gbe e le awọn ẹya Hausa ti wọn n gbe lagbegbe Dọpẹmu lọwọ.

Ṣaaju akoko yii lawọn Hausa ọhun ti ya wa sagbegbe iṣẹlẹ naa pẹlu oniruuru nnkan ija oloro lọwọ wọn”.

Ọgbẹni Bọlaji Ọrẹagba, ti i ṣe ọga agba ajọ LASTMA, waa rọ awọn awakọ tirela atawọn onimọto laarin ilu, lati ṣọra fun ere asaju, ki wọn si maa kiyesi awọn ami to wa loju titi fawọn to n wa mọto jake-jado ipinlẹ naa. Bẹẹ lo tun ba awọn mọlẹbi oloogbe kẹdun pe Ọlọrun yoo rọ wọn loju, ọjọ yoo si jinna sira wọn.

Leave a Reply