Monisọla Saka
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta ti tẹ afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan, Amadasu Victor, lasiko to n dunaadura lori bo ṣe fẹẹ ra ibọn AK-47 lọwọ ẹni to n ta a.
Gẹgẹ bi Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ naa, Bright Edafe, ṣe fidi ẹ mulẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, o ni nibi ti afurasi ọhun ti n na ibọn alayinyipo nla AK-47 si miliọnu kan ati ọọdunrun Naira (1.3 million), lati le fi di olori ogbologboo ẹgbẹ okunkun ti wọn n pe ni Vikings Confraternity, lagbegbe naa, ni wọn ti nawọ gan an.
O ni, “Nibi i ti ọkunrin yii ti n na ibọn AK-47 pe miliọnu kan Naira o le loun yoo san fawọn ajinigbe ti wọn fẹẹ ta a fun un la ti ri i. O ni oun n ṣakitiyan lati di olori ẹgbẹ okunkun Vikings Confraternity ni, ati pe ọkan lara awọn nnkan teeyan fi gbọdọ jẹ olori ni lati ni ibọn nla AK-47, o kere tan.
Amadasu fẹnu ara ẹ jẹwọ pe wọn mu oun nitori ibọn AK-47 toun fẹẹ ra ni.
“Wọn ni ki n ra ibọn AK-47, nitori mo fẹẹ jẹ olori fun ẹgbẹ okunkun Vikings”.
Nigba to n ṣalaye ara ẹ, Amadasu ni, “Mo ni ileeṣẹ kekere ti wọn ti maa n fọ mọto (car wash), bẹẹ ni mo tun n ṣe Yahoo Yahoo. Mo maa n tan awọn obinrin oyinbo lori ayelujara pe mo nifẹẹ wọn, wọn aa si fowo ranṣẹ si mi. Mo maa n pa bii miliọnu mẹjọ Naira nigba mi-in, bẹẹ ni mo maa n pin fawọn eeyan ti wọn ba fun mi niru iṣẹ bẹẹ ninu owo ọhun”.
Afurasi to kabaamọ pe o ti to ọdun mẹfa toun ti wa ninu ẹgbẹ okunkun naa ni nisinyii loju oun la, toun si mọ pe oun ko jẹ nnkan kan, nitori oun ko jere kan bo ti wu ko mọ ninu ẹgbẹ ti oun n ṣe ọhun. O ni ko si ere kankan ninu ẹgbẹ okunkun ṣiṣe.