*Idi abajọ ree o
Idi Theophilous Akindele ko le ṣe ko ma domi, idi rẹ yoo domi, nitori gẹgẹ bii olori ileeṣẹ to n ṣeto ibanisọrọ ijọba apapọ, ọga agba ni nileeṣẹ tẹlifoonu patapata, o mọ Ọgagun Muritala Muhammed daadaa. Ẹẹmeji ni wọn ti pade, ṣugbọn ẹẹmejeeji, alaafia kọ ni wọn fi tuka. Muritala ni olori ẹka awọn ologun to n ri si eto ibanisọrọ, bii tẹlifoonu ni o, ati awọn irinṣẹ ti wọn n lo lati maa fi ba awọn ọmọ ogun wọn sọrọ tabi ileeṣẹ ologun gbogbo sọrọ kaakiri, bo ṣe nilẹ yii tabi loke-okun. Nidii eyi, gbogbo igba ni wọn maa n lo irinṣẹ oriṣiiriṣii, gbogbo igba ni wọn si maa n lo awọn oṣiṣẹ lati ileeṣẹ eleto ibanisọrọ yii. Eeyan ko si le ṣe ooṣa lodo ki labẹlabẹ ma mọ, ko sohun ti wọn yoo ṣe ti Akindele ko ni i mọ, paapaa nigba to ti di ọga patapata fun ileeṣẹ naa, to si jẹ abẹ rẹ ni awọn ọmọọṣẹ gbogbo ti n jade lọ.
Ni ọjọ kan, Akindele jokoo si ọọfiisi rẹ, bẹẹ ni akọwe agba nileeṣẹ to n ri si eto inawo ijọba apapọ, Abdul Atta, fi faili kan ranṣẹ si i, o ni ko ba oun wo o kiakia, ko si gba oun nimọran lori ohun to yẹ ki oun ṣe. Faili naa jẹ ti ileeṣẹ ologun, wọn ṣẹṣẹ ko irinṣẹ kan wọlu ni, irinṣẹ naa pọ diẹ, wọn si ti ra a, ohun to ku ni ki ijọba san owo rẹ. Owo ti wọn kọ pọ gan-an, ṣugbọn eyi kọ ni iṣoro ibẹ, nitori owo kuku wa lapo ijọba Gowon aye ọjọ naa. Ohun ti Atta fẹẹ mọ ni boya irinṣẹ naa to iye owo ti wọn kọ pe o jẹ ko too di pe wọn sanwo fun wọn. Attah ti mọ pe bi ẹni kan ba wa nibi kan to le sọ bi ọrọ naa ti jẹ foun gan-an, Akindele ti i ṣe ọga agba pata ni ẹka eto ibanisọrọ yii ni. Nitori ẹ lo ṣe gbe faili naa fun un. Nigba ti Akindele yẹ faili wo sọtun-un, to yẹ ẹ wo sosi, to yẹ awọn irinṣẹ ti wọn darukọ wọnyi wo, ohun to kọ sinu faili naa ree:
“Irinṣẹ ti wọn ra yii ti pẹ nigba, koda, ọjọ ti lọ lori rẹ. Bii ọdun meje sẹyin, iyẹn ni 1963, ni wọn ti ṣe irinṣẹ mi-in, iru eleyii gan-an, ṣugbọn to jẹ ti igbalode. Awọn ti wọn ra iru irinṣẹ bayii wa kan n da owo Naijiria sinu omi okun lasan ni, nitori ohun ti wọn ra yii ko ni i wulo fẹni kan, tabi fun ileeṣẹ wọn paapaa, ifowoṣofo lasan ni. Ohun ti wọn tori rẹ sọ pe awọn ra irinṣẹ yii, irinṣẹ naa ko ni i ṣee lo fun un, ko si sidii kan ti ẹnikẹni fi gbọdọ ko owo le iru irinṣẹ bẹẹ, tabi ti yoo ni ki wọn ko o wa fawọn. Nitori bẹẹ, ẹni yoowu to jẹ to ra iru irinṣẹ yii, tabi to ni ki wọn ko o wa fun ijọba Naijiria, tọhun gbọdọ jiya, bẹẹ ni wọn gbọdọ gba ninu owo to na danu yii lọwọ oun funra ẹ, ki wọn ni ko san ninu owo irinṣẹ buruku to ra, ko le mọ pe ohun ti oun ṣe ko dara.”
Ọdun 1970 leleyii ṣẹlẹ, Akindele ko ti i pade Muritala ri, ohun to kan mọ ni pe ileeṣẹ ITT lo ta irinṣẹ buruku bẹẹ fun wọn.
N loun ba kọwe, o si fi faili ranṣẹ pada si ẹni to gbe e fun un. Oun ko ranti ọrọ naa mọ, o n ba iṣẹ rẹ lọ. O to ọjọ kẹrin ti ọrọ yii ṣẹlẹ ni awọn ọga ṣọja meji ba wọ ọọfiisi rẹ lai kan ilẹkun, bẹẹ ni wọn ko si duro lọdọ sẹkitiri ẹ ko le lọọ sọ fun ọga rẹ pe ẹni kan fẹẹ waa ri i, wọn ja wọle bẹẹ ni. Asiko naa jẹ asiko ti ogun abẹle ṣẹṣẹ pari, to jẹ ko si ibi ti awọn eeyan ti ri ṣọja ti wọn ki i ṣe ẹrujẹjẹ, agaga bi wọn ba waa jẹ ọga ṣọja bẹẹ, kaluku yoo fi ara ṣoko ni. Awọn ṣọja eleyii tilẹ waa yatọ, ọkan ninu wọn ga firigbọn, ibinu ni wọn si tun n ba bọ, ko sẹni kan ti wọn bi daadaa ti yoo duro loju ọna, kaluku sa danu ni. Laye igba naa, ko sẹni ti yoo ni Lebe ko pọn ọmọọre, ko ṣeni ti yoo duro beere ọrọ lọwọ ṣọja, ohun ti ṣọja ba ṣe, aṣegbe ni. Nitori bẹẹ lo ṣe jẹ ko sẹni kan to le da awọn ṣọja meji yii duro, ọkan jẹ ọga gidi, ikeji si jẹ ọọfisa to tẹle e.
Eyi to jẹ ọga yii, Kọnẹeli ni ninu iṣẹ ṣọja, awọn ọga igba naa niyẹn. Bo ṣe wọle lo leju koko mọ Akindele, iyẹn ti ko si ti i mọ ohun to n ṣẹlẹ, ti ẹni to si wa siwaju ẹ ko sọ pe oun n bọ tẹlẹ, ti ko si mọ ẹni to jẹ, niṣẹ lo dorikodo sibi iwe to n ka, nitori awọn ti wọn wọle naa ko kuku ki i. Nigba ti ko wo oju wọn yii, eyi to jẹ ọga fibinu ju faili kan si ori tabili ẹ. Lẹyin naa lo fi ohun ramuramu sọ pe ‘Nigba mi-in, ma maa kọ ikọkukọ bayii nipa ẹka ibanisọrọ ileeṣẹ ologun o, nijọ mi-ni ti o ba tun ṣe bẹẹ, mo maa ni ki wọn yinbọn pa ẹ ni!’ Akindele naa ki i ṣe eeyan daadaa kan tọrọ ba da bẹẹ, oun naa ki i pẹẹ binu rara. Nigba ti ọga yii ti sọ ohun to sọ yii, inu ti bi oun naa kọja aala. O jọ pe ohun to dun un ju ni pe bawo ni ẹni kan ti oun ko mọ ri yoo ṣe deede ja wọ ọọfiisi oun, oun naa toun jẹ ọga pata laaye oun, ti yoo si maa halẹ bayii mọ oun.
N lo ba dide naro si ṣọja, ohun to si sọ fun un ni pe. “Wo o, Ọgbẹni Kọnẹeli, bi ki i baa ṣe aṣọ ijọba to o wọ sọrun, ṣe o mọ pe oo kan le deede ja wọ ọọfiisi mi ko o maa ṣe bo o ti n ṣe yii! Nitori bẹẹ, jade nibi yii, ko o sare jade bo o ṣe sare wọle, ki ibinu emi naa too di nnkan mi-in mọ ẹ lọwọ. Nigba mi-in, ki o si kọ ẹkọ iwa ọmọluabi, pe bi eeyan ba de ọdọ ẹni ti ko mọ ri, eeyan n huwa daadaa ni. Ọga ṣọja ko mọ pe ẹni kan yoo sọ bẹẹ soun laelae, o si wo Akindele lati oke de isalẹ, bo si ti n wo o yii, akọda to tẹle e ti mu ọwọ lọ sibi bẹliiti ẹ, o fẹẹ yọ ibọn to fi ha sibẹ. Ṣugbọn ọga rẹ sọ pe ko ma yọ ara ẹ lẹnu, o ni ko jẹ kawọn maa lọ, n lawọn mejeeji ba fibinu jade bi wọn ti fibinu wọle. Wọn n lọ kemọkemọ. Igba ti wọn lọ tan ni awọn oṣiṣẹ to ti sa lọ tẹlẹ too bẹrẹ si i pada wa, wọn waa wo Akindele, paapaa nigba ti wọn ko gbọ iro ibọn.
Bi awọn ṣọja naa ti jade ni Akindele pe Attah to gbe iṣẹ fun un nijọsi pada, lo ba ṣalaye pe ki lo n ṣe, ọga ṣọja kan ma ṣẹṣẹ wa sibi yii to ni oun yoo yinbọn foun ma ni. Attah ni ko juwe ṣọja naa, nigba to si juwe ẹ, Attah ni, Ọgagun M.R. Muhammed niyẹn, oun ni olori ẹka eto ibanisọrọ awọn ṣọja. O ni ki Akindele ma dahun, ko maa ṣiṣẹ tirẹ lọ, ko ṣaa mọ bi yoo ti maa ṣe pẹlu wọn, pe oniwahala kan ni wọn. Lẹyin eyi ni akọwe agba fun ileeṣẹ tiwọn naa, Ọgbẹni Lawson, pada waa ba Akindele, o ni ko ma maa ṣe aya gbangba bẹẹ yẹn mọ si awọn ṣọja o, pe to ba jẹ wọn yinbọn pa a bẹẹ, ko si ohun ti yoo ṣẹlẹ o, nitori awọn ni wọn n ṣejọba, awọn nijọba wa lọwọ rẹ, ohun ti wọn ba si ṣe, aṣegbe ni o. Akindele dupẹ dupẹ, o loun gbọ, oun yoo maa ṣọ ara oun, igba akọkọ si niyẹn ti oun ati Muritala kọkọ pade ara wọn. Ni 1970.
Ko si ẹni ti yoo gbọ iroyin iku bẹẹ ti yoo tun maa ṣe agidi, afi to ba ṣe pe nnkan mi-in wa nibẹ fun tọhun nikan ni. Firifiri ti Akindele ri yii ti mu ko sọ pe lọjọ mi-in ti oun ba tun ni anfaani lati pade Muritala, oun yoo ri i pe awọn ko fija tuka, yoo si le ri i pe eeyan daadaa loun naa i ṣe. Ṣugbọn lẹyin ti wọn ti rira ni 1970 yii, wọn ko tun rira mọ, afi ni 1973, ọdun kẹta lẹyin ti wọn ti kọkọ pade lakọọkọ. Ipo kan naa ti wọn wa nijọsi naa ni awọn mejeeji tun wa. Akindele ni olori ẹka ibanisọrọ to n ri si ọrọ tẹlifoonu jake-jado Naijiria, Muritala si ni olori eto ibanisọrọ nileeṣẹ awọn ologun ilẹ wa. Ijọba apapọ lo ni iṣẹ to gbe awọn mejeeji pade, ohun to si ta koko nibẹ ni pe Akindele ko mọ pe Muritala ni yoo ba pade, Muritala naa ko mọ pe Akindele naa loun yoo tun ba pade, afi bawọn mejeeji ṣe tun pade ara wọn ganboro. O ṣe ni laaanu pe ipade naa ko tun mu eeso rere kan dani, ajatuka ni ti agbaarin ni wọn fi i ṣe!
Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.
Ok