Florence Babaṣọla
Baba agba ẹni ọdun mẹrindinlaaadọrin, Adeleke Joseph, ladajọ Majisreeti kan niluu Ileefẹ, ti paṣẹ pe ki wọn lọọ fi pamọ sọgba ẹwọn lori ẹsun ole jija ati gbigba ẹru-ole sọdọ ti wọn fi kan an.
Inspẹkitọ Elijah Adeṣina to jẹ agbefọba ṣalaye pe laarin ọjọ kẹta si ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun yii, ni olujẹjọ atawọn alabaaṣiṣẹpọ rẹ ti wọn ti sa lọ bayii huwa naa.
Adeṣina sọ siwaju pe lagbegbe Mọọrẹ ati Lafogido, niluu Ileefẹ, ni wọn ti ja ọkẹ aimọye eeyan lole foonu ati owo wọn.
Foonu ati owo Ọgbẹni Akinọla Oluwaṣeyi ti apapọ owo rẹ jẹ ẹgbẹrun nejidinlogun naira ni wọn kọkọ ji, wọn tun ji foonu Tecno Spark 4 to jẹ ti Ọgbẹni Micheal Oluwagbemileke.
Foonu meji to jẹ ti Ọgbẹni Adejuwọn Folusọ, bẹẹ ni wọn tun ji Itel A56 to jẹ ti Ismail Agbaje ti owo rẹ si to ẹgbẹrun marundinlogoji naira ni wọn tun ji.
Bakan naa lo ni awọn ọlọpaa ba foonu Samsung kan lọwọ Adeleke, ti ko si le sọ ibi to ti ri i. Adeṣina fi kun ọrọ rẹ pe wọn tun ka igbo (indian hemp) mọ baba naa lọwọ.
Gbogbo ẹsun mẹrẹẹrin ti wọn fi kan olujẹjọ lo sọ pe oun ko jẹbi, agbẹjọro rẹ naa, Unah Sunday, si bẹ kootu lati fun un ni beeli lọna irọrun.
Majisreeti A. A. Adebayọ kọ lati fun olujẹjọ ni beeli, o paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa lọọ fi i pamọ sọgba ẹwọn ilu Ileṣa titi di ọjọ kejilelogun, oṣu kẹta, tigbẹẹjọ yoo tun waye lori ọrọ rẹ.