Nipinlẹ Ogun ati Ọyọ, Tinubu lo n ṣaaju wọn

Jọkẹ Amọri

Ni bi a ti n kọ iroyin yii, ijọba ibilẹ mejila ni wọn ti kede awọn ti wọn wọle nibẹ ninu ibo aarẹ ti a di lọjọ Satide yii o. Ṣugbọn ni gbogbo ibi ti wọn ti kede esi yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti ẹgbẹ APC, lo ta awọn to ku yọ. Nibẹ lo ti fẹyin Atiku Abubakar ti ẹgbẹ PDP janlẹ, to si le Peter Obi ti ẹgbẹ Labour naa sẹyin patapata.

Awọn ijọba ibile ti Tinubu ti rọwọ mu ni ipinlẹ Ọyọ yii ni Ibadan North West, Kajọla, Afijio, Itẹsiwaju, Atisbo, Atiba, Lagelu, Ọyọ West, Isẹyin, Ibarapa East, Saki East, Ibarapa Central, Ibarapa North ati Ọyọ East. Ọjọgbọn Babatunde Oluṣọla ti i ṣe alakooso eto akojọ ibo nipinlẹ naa lo kede eleyii, to ni awọn to ku n bọ lọna, iṣẹ naa n lọ.

Bakan naa lo jẹ nipinlẹ Ogun, awọn ijọba ibilẹ mẹwaa ti wọn ti ka ibo nibẹ bayii, Tinubu lo wọle. Loootọ lawọn alatako rẹ, Atiku ati Peter Obi, ja raburabu, ṣugbọn sibẹ naa, oun lo ta gbogbo wọn yọ.

Awọn ijọba ibilẹ ti Tinubu ti na wọn yii ni Rẹmọ North, Ẹgbado South, Ikẹnnẹ, Ewekoro ati Abẹokuta North. Awọn to ku ni Ijẹbu North, Ijẹbu North-East, Imẹkọ Afọn, Ọdẹda ati Ijẹbu Ode. Alakooso eto akojọ ibo nibẹ, Ọjọgbọn Kayọde Oyebọde Adebọwale ti Yunifasiti Ibadan lo kede awọn esi naa, pẹlu idaniloju pe awọn to ku n bọ laipẹ rara.

Bi ibo naa ti n lọ bayii, ati pẹlu ikede awọn INEC, ko ti i si ondupo aarẹ mi-in to n rọwọ mu lawọn ipinlẹ ilẹ Yoruba ti wọn ti kede esi wọn, Aṣiwaju Bọla Tinubu nikan ni.

Leave a Reply