Adewale Adeoye
Titi di akoko ta a n ko iroyin yii jọ lawọn ọlọpaa teṣan agbegbe Ilajẹ-Ajah, nipinlẹ Eko, ṣi n wa Ọgbẹni Taiwo Adebayọ, ọmọ baba onile kan to wa l’Ojule kẹrinlelogun, Opopona Adewumi, niluu Ilajẹ-Ajah. Ẹsun tawọn ọlọpaa fi kan an ni pe o gun Oloogbe Shina Oluwaṣẹgun ti i ṣe ọkan lara awọn ayalegbe baba rẹ pa nitori aaye igbọkọsi tawọn mejeeji n ja si.
ALAROYE gbọ pe ni aṣaale ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla yii, ni Taiwo lọọ ji oloogbe naa lẹyin to ti sun lẹyin to de lati ẹnu iṣẹ dẹrẹba ọkọ akero to n ṣe lagbegbe naa pẹlu mọto korope rẹ kan. Ohun ti Taiwo n fẹ lọwọ oloogbe naa ni pe ko waa gbe mọto korope to fi n ṣiṣẹ kuro nibi to paaki rẹ si, wọn ni ibi to gbe e si ko bojumu. Ṣugbọn nigba ti oloogbe maa debi to paaki mọto rẹ si o ri i pe ibi gan-an toun maa n paaki ọkọ oun si lati aimọye oṣu sẹyin naa lo wa. Gbogbo akitiyan oloogbe lati sọ fun ọmọ baba lanlọọdu rẹ pe oun ko kọja aaye oun ni ko wọ ọ leti rara, to si faake kọri pe afi ko gbe mọto rẹ kuro nibi to wa. Bi oloogbe ṣe wọnu mọto naa lati wa a kuro ni Taiwo ba tun yọ ọbẹ aṣooro kekere kan to wa lapo rẹ jade, to si bẹrẹ si i fi gun oloogbe yannayanna ni gbogbo ara.
Ọgbẹni Matthew toun naa jẹ ọkan lara awọn ayalegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye sọ pe niṣoju oun niṣẹlẹ ọhun fi waye, ati pe ariwo lasan lawọn mejeeji n pa mọ ara wọn telẹ, nigba to ya ni oloogbe ba gbiyanju lati gbe mọto rẹ kuro nibi to n bi Taiwo ninu, lai mọ pe ọbẹ wa lọwọ Taiwo, to si fi gun un pa.
Ọgbẹni Shonibarẹ Faid ti i ṣe ẹgbọn oloogbe naa loun gba ipe pajawiri kan ni, nigba toun si maa dele taburo oun n gbe, ṣe loun ba a ninu agbara ẹjẹ to ti ku silẹ, ati pe mọṣuari ileewosan ‘Mainland Hospital, to wa niluu Yaba, nipinlẹ Eko lawọn gbe e lọ.
O ni, ‘‘Mo ti lọọ fiṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa agbegbe ibi ti aburo mi n gbe leti, mo ṣalaye gbogbo ohun tawọn eeyan sọ fun mi nipa iṣẹlẹ to gbẹmi rẹ fun wọn pata. O yẹ ka ti lọọ ṣeto isinku rẹ ni ilana ẹsin Islaamu, ṣugbọn awọn ọlọpaa lo ni ka duro na, kawọn ṣayẹwo sara oloogbe naa lati mọ koko ohun to pa a.
Ohun to n bi mi ninu nipa ọrọ ọhun ni pe awọn kọọkan tọrọ naa ṣoju wọn sọ pe ṣe niya to bi ọdaran naa, iyẹn iyawo lanlọọdu, n sọ fọmọ rẹ pe ko tẹra mọ ọn bo ṣe n gun oloogbe titi to fi ku.
Ati iyawo onile ti i ṣe iya to bi Taiwo, ati awọn araale gbogbo ni wọn ti sa lọ bayii, ibẹru pe kawọn ọlọpaa ma waa ko gbogbo wọn fohun ti wọn ko mọ nipa rẹ tabi kawọn ọdọ adugbo tinu n bi waa koju ija si wọn lo fa a ti wọn fi sa kuro nile bayii.