Nitori ara rẹ ti ko ya, IPOB ni ki ijọba apapọ tu Kanu silẹ

Adewale Adeoye

Ẹgbẹ ẹya Ibo ti wọn n pe ni ‘ The Proscribed Indigenous People Of Biafra’ (IPOB), ti kegbajare pe ki ijọba apapọ yọnda ọkan pataki lara olori ẹya Ibo nilẹ yii, Nnamdi Kanu, to wa lahaamọ ijọba apapọ, ko maa lọ sile rẹ pẹlu bi ara rẹ ko ṣe ya ninu ọgba ẹwọn to wa bayii.

Ẹgbẹ naa ni idi pataki tawọn ṣe ni ki awọn alaṣe ijọba tu Nnamdi Kanu silẹ ko maa lọọ sile ni pe ile-ẹjọ kan nilẹ yii ti da a lare, ti wọn si ti sọ pe ki ijọba fi i silẹ, ṣugbọn to jẹ pe ṣe ni wọn ko tẹle aṣẹ ti kootu naa pa fun wọn rara.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ẹgbẹ IPOB, Emma Powerful, fi sita lori ọrọ ọhun lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii to tẹ ALAROYE lọwọ ni wọn ti sọ pe, ‘Ohun ta a gbọ lati ẹnu ọkan lara awọn lọọya wa ti wọn lọọ ṣabẹwo si Nnamdi Kanu ninu ọgba ẹwọn too wa ni pe ori aarẹ gidi lo wa bayii, ko le jẹun rara, bẹẹ lo n bi, gbogbo ohun to ba fi kan ẹnu lo n pọ jade nitori lilu tawọn ọlọpaa DSS ilẹ wa fi ṣe tiẹ nigba ti wọn mu un, ara rẹ ko ya rara, bebe iku la gbọ pe o wa bayii o.

‘ Bẹ o ba gbagbe, Nnamdi Kanu ni ipenija aisan kan to n ṣe e tẹlẹ, eyi tawọn ọlọpaa DSS ilẹ wa ko ṣe amojuto rẹ daadaa rara, bẹẹ ni wọn ko jẹ ki awọn dokita rẹ yọju si i lati ṣetọju rẹ gẹgẹ bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ fun gbogbo akoko to fi wa lọdo wọn bayii.

‘‘Ohun ta a ṣakiyesi nipa aisan ojiji to kọ lu u bayii ni pe ko ri ounjẹ gidi kan jẹ rara ninu ọgba ẹwọn to wa lọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ yii, bẹẹ lo tun jẹ pe lilu ti wọn lu u bajẹ yẹn tun hu awọn aisan miiran jade lara rẹ, to si nilo itọju gidi bayii.

‘’ Ohun ta a n beere fun lọwọ ijọba ilẹ yii ni pe ki wọn ju Kanu silẹ ko maa lọ sile rẹ layọ ati alaafia, nitori pe ile-ẹjọ kan nilẹ yii ti paṣẹ fun wọn pe ki wọn da a silẹ, ṣugbọn ti wọn ko tẹle aṣẹ naa rara.’’

Leave a Reply