Nitori ariwo, ijọba ti ṣọọṣi atawọn ile ounjẹ igbalode kan pa l’Ekoo

Monisọla Saka

Ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko to n ri si ọrọ ayika, Lagos State Environmental Protection Agency (LASEPA), ti gba kọkọrọ mọ ẹnu ọna ile ounjẹ igbalode mẹta to gbajumọ daadaa nipinlẹ Eko, ṣọọṣi atawọn ileeṣẹ mi-in lagbegbe Surulere ati Orile-Iganmu, nipinlẹ Eko, nitori apọju ariwo ti wọn fi n da adugbo laamu.

Lai fi ti ikilọ aimọye igba lati ileeṣẹ naa ṣe, awọn ibi ti wọn ti pa yii, ni wọn ni wọn kọ eti ikun si akiyesi ti ileeṣẹ LASEPA n pe wọn si, ki wọn too lọọ ti wọn pa.

Loju opo ayelujara ni wọn fi atẹjade si pe awọn wọde lati fopin si ariwo to n di adugbo lọwọ, atawọn nnkan to lodi mi-in ti wọn n ṣe lagbegbe Surulere ati Orile-Iganmu.

Lara awọn ileeṣẹ ti ko tẹle ofin ati ilana ti ajọ LASEPA fi lelẹ ti wọn ti ti ileeṣẹ wọn pa titi ti wọn yoo fi ṣe ohun to tọ ni: Red Pepper Bites Limited, Lacibo Restaurant and Lounge, ati Krusty Bakery and Pastries.

Awọn yooku ni, Addie, Don Nelson Resort and Suites, ati ile ijọsin Revelation Christian Ministry.

Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna fọrọ omi ati ayika nipinlẹ Eko, Tokunbọ Wahab, fi sita l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, lo ti ni, “Ileeṣẹ LASEPA ṣiṣẹ yika awọn agbegbe kan lojuna ati le wawọ ariwo pipa to n daamu adugbo atawọn iwa to lodi si gbigbe ni adugbo kan lagbegbe Surulere ati Orile Iganmu, nipinlẹ Eko bọlẹ.

“Pẹlu gbogbo ikilọ ta a ti ṣe fawọn ileeṣẹ yii, wọn ko tori ẹ ma tapa si aṣẹ LASEPA. Nitori bẹẹ ni a ṣe ti awọn ileeṣẹ to rufin yii pa fungba diẹ, lati ri i daju pe wọn tẹle gbogbo nnkan ta a la kalẹ fun wọn lori ofin agbegbe.

“Awọn ileeṣẹ tọrọ yii kan yii yoo wa ni titi pa, lati le fi kọ awọn ara yooku lọgbọn.

Leave a Reply