Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkan ninu awọn Fulani to n ji awọn eeyan gbe lagbegbe Akoko ni wọn lo pade iku ojiji lasiko ti awọn darandaran ọhun atawọn fijilante doju ija kọ ara wọn ninu igbo kan to wa lagbegbe Akunnu Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu Ọmọọba Tọlani Orogun to jẹ Adele-Ọba ilu Akunnu, o ni ọsẹ to kọja lawọn Fulani ajinigbe ọhun da awọn arinrinajo kan lọna lasiko ti wọn n lọ si apa Oke-Ọya, ti wọn sì fipa ko awọn mejeeje wọnu igbo lọ.
Eyi lo ṣokunfa bawọn fijilante, ọdẹ atawọn ọdọ kan ṣe ko ara wọn jọ lopin ọsẹ to kọja lati lọọ gba awọn ti wọn ji gbe ọhun silẹ lọwọ awọn darandaran to ji wọn gbe.
O ni awọn Fulani ọhun ni wọn kọkọ mura ija pẹlu bi wọn ṣe da ibọn bolẹ bi wọn ṣe kofiri awọn eeyan naa ninu igbo ti wọn sa pamọ si.
Ibi tawọn igun mejeeji ti n dana ibọn fun ara wọn ni ọkan ninu awọn oniṣẹẹbi naa ti fara gbọta, to si ku loju ẹsẹ, ohun to ba awọn ẹgbẹ rẹ yooku lẹru ree ti wọn fi gbagbe ọrọ awọn ti wọn mu nigbekun, ti olukuluku wọn si bẹsẹ rẹ sọrọ.
Eyi lo fun awọn fijilante naa lanfaani lati ri gbogbo awọn arinrinajo mejeeje tu silẹ lai fara pa, bẹẹ ni wọn tun gbe oku Fulani ọhun lọ si mọṣuari ileewosan ijọba to wa n’Ikarẹ.
Ọmọọba Orogun ni ki i ṣe ipenija kekere lawọn eeyan Akunnu, Auga ati Ikakumọ Akoko n koju lọwọ awọn ọdaran Fulani latari aala ipinlẹ Edo ati Kogi ti awọn ilu ọhun wa.
O rọ ijọba lati ṣeto ọpọlọpọ awọn ẹsọ alaabo ti yoo maa peṣe aabo fawọn eeyan agbegbe naa ki wọn le raaye gbaju mọ isẹ wọn.