Dada Ajikanje
Ẹgbẹ oṣelu PDP ti bu ẹnu atẹ lu ọwọ ti Aarẹ Muahmmadu Buhari fi mu ọrọ awọn ọlọpaa mẹfa tawọn ajinigbe ji, ti wọn si n beere fun ọgọrun-un miliọnu naira fun itusilẹ wọn.
Wọn ni dipo ki Buhari wa bi awọn ọlọpaa mẹfa yii yoo ṣe bọ lọwọ awọn janduku ajinigbe, niṣe lo n dunnu lori bi ọkan ninu awọn gomina ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe darapọ mọ APC, iyẹn Gomina David Umahi, ti ipinlẹ Ebonyi.
O ni kani gbogbo ipa ati agbara ti Aarẹ n sa lori ọrọ oṣelu inu ẹgbẹ APC lo ba n lo lori bi nnkan yoo ṣe rọrun ni Naijiria ni, ayipada nla yoo ti ba awọn eeyan orilẹ-ede yii daadaa.
Ṣa o, Igbakeji alukoro agba fun ẹgbẹ oṣelu APC, Yekinni Nabena, naa ti sọrọ, o ni ti gbogbo eeyan ba n sọ pe eto aabo mẹhẹ, ko tọ si ẹgbẹ oṣelu PDP lẹnu, nitori lasiko tiwọn naa ni gbogbo wahala ọrọ aabo to ri rudurudu yii ti bẹrẹ. O ni ara lo n ta wọn bi Gomina Umahi to jẹ ẹja nla ninu ẹgbẹ wọn ṣe kuro ninu ẹgbẹ ọhun waa darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Ọkunrin yii sọ pe ka ni wọn ṣe ohun to yẹ lasiko igba ti wọn n pawo rẹpẹtẹ lori owo-epo rọbi, ti wọn si na owo ọhun lori idagbasoke Naijiria, orilẹ-ede yii iba ti dara ju bayii lọ.
O ni, wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ ni o, ọpọlọpọ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn ṣi n bọ waa darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Laipẹ yii lawọn ọlọpaa mẹjọ kan kuro nipinlẹ Borno, ti wọn n lọ si Zamfara, lẹyin ti iṣẹ wọn ti pari ni Maiduguri, ipinlẹ Borno.
Ipinlẹ Katsina ni wọn sọ pe wọn de, ti awọn ajinigbe fi kọlu wọn, ti meji si raaye sa mọ awọn janduku ọhun lọwọ. Ọkan ninu awọn meji to sa yii ko ṣai fara gbọta. Ẹsẹ ni wọn sọ pe wọn ti yin in nibọn, ti awọn ara abule to sa wọ si sare gbe e lo si teṣan ọlọpaa, nibẹ naa lo si gba de ọsibitu, ti awọn ọlọpaa mẹfa yooku ṣi wa lọwọ awọn ajinigbe.
Ọgọrun-un miliọnu naira ni wọn kọkọ sọ pe ki wọn lọọ mu wa, nigba to ya ni wọn ni ki wọn lọọ mu idaji miliọnu wa fun ẹni kọọkan, ti apapọ ẹ si jẹ miliọnu mẹta naira fun awọn ọlọpaa mẹfẹẹfa.
Agbegbe kan ti wọn n pe ni Dogondaji ni wọn ti kọlu wọn nipinlẹ Katsina, ninu igbo kijikiji kan, ti wọn si n beere fun owo nla nla ki wọn too le ko wọn silẹ bayii.