Faith Adebọla, Eko
Latari iku ojiji to pa ọkan lara awọn akẹkọọ wọn, Sylvester Oromoni, ọmọọdun mejila, ti iku ọhun si da awuyewuye silẹ, ijọba ipinlẹ Eko ti paṣẹ pe kawọn agbofinro lọọ fi agadagodo nla ti ileewe Dowen College, to wa lagbegbe Lẹkki, l’Ekoo, pa.
Aṣẹ yii wa ninu atẹjade kan ti wọn fi lede lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu kejila yii, eyi ti Igbakeji Alakooso Alukoro ileeṣẹ eto ẹkọ ipinlẹ Eko, Ganiu Lawal fọwọ si.
Atẹjade naa sọ pe Kọmiṣanna eto ẹkọ, Abilekọ Fọlaṣade Adefisayọ, paṣẹ titi ileewe naa pa loju-ẹsẹ, ki aaye le wa lati ṣewadii to lọọrin si iṣẹlẹ ibanujẹ naa.
Ọjọ Ẹti, Furaidee yii, lawọn ikọ ijọba, lati ẹka ileeṣẹ eto ẹkọ ṣabẹwo pajawiri sileewe naa, wọn lọ yika gbogbo ọgba ati yara ikawe, wọn si ṣepade pẹlu awọn adari ileewe ọhun.
Kọmiṣanna Adefisayọ kẹdun iku ojiji to waye naa, o si rọ awọn obi ati araalu lati ni suuru, ki ijọba le ṣewadii bo ṣe yẹ lori iṣẹlẹ ọhun, o ni gbogbo ẹni to ba jẹbi lori ọrọ naa ni yoo ri pipọn oju ijọba.
Ṣe l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni mọlẹbi Oromoni kan, Ọgbẹni Perrison Oromoni, ṣalaye sori atẹ ayelujara tuita rẹ pe awọn ọmọọlewe ẹlẹgbẹ Sylvester kan fipa mu oloogbe naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, ọṣu kọkanla to kọja yii, wọn ni ko dara pọ mọ ẹgbẹ okunkun tawọn n ṣe lọran-an-yan, nigba ti akẹkọọ naa loun o ṣẹgbẹ, ni wọn ba bẹrẹ si i lu lalubami, ti wọn si fipa rọ kẹmika buruku si i lọfun.
Akọlu ọhun ni wọn lo ṣakọba fun ilera ọmọde yii, asian da a gbalẹ, ọjọ kẹrin lẹyin iṣẹlẹ buruku ọhun, iyẹn ọjọ Tusidee, lo gbẹmi-in mi nileewosan ti wọn ti n tọju ẹ.
Perrison ni ayẹwo iṣegun ti wọn ṣe fun un fihan pe ilukulu ti wọn lu ọmọ naa pọ ju ohun ti agbara ẹ le gbe lọ, wọn ni o ti gbọgbẹ ninu, eyi to pada ja si iku fun un.
Ọkunrin naa tun fẹsun kan awọn alaṣẹ ileewe Dowen pe alabosi ni wọn, o ni wọn pe baba oloogbe naa lori aago, wọn si purọ fun un pe ki i ṣawọn ẹlẹgbẹ okunkun lo lu ọmọ rẹ o, niṣe loloogbe naa ṣeṣe lasiko to n gba bọọlu pẹlu awọn ẹlẹgbẹ rẹ.
Amọ, ninu atẹjade kan ti Ọga agba ileewe naa, Abilekọ Adebisi Layiwọla, fi lede l’Ọjọruu, Wẹsidee, lori ẹsun ti wọn fi kan ileewe naa, o ni o ya oun lẹnu lati gbọ iru ẹsun bẹẹ nipa awọn.
O ni lẹsẹkẹsẹ ti wọn lọmọleewe yii fara pa nibi toun atawọn ẹlẹgbẹ ẹ ti n gba bọọlu lawọn ti bẹrẹ si i fun un ni itọju iṣegun, wọn ni dokita kan wa ni sẹpẹ ninu ọgba ileewe naa to bẹrẹ si i tọju ẹ ni pajawiri, bi wọn ṣe n lo oogun kan ti wọn pe ni Ibuprofen fun un lati din irora ẹ ku, bẹẹ ni nọọsi n fọwọ wọ ọ lara lati na eegun ati iṣan ara rẹ.
Ohun ta a gbọ ni pe awọn obi ọmọdekunrin naa ti kọwe ẹsun si awọn ọlọpaa ati ijọba ipinlẹ Eko pe ki wọn ba awọn wadii okodoro otitọ nipa iku ọmọ wọn yii.
Wọn ni baba oloogbe naa sọ pe ki ọmọ naa too dakẹ lọsibitu, o jẹwọ fun baba rẹ pe ki i ṣe bọọlu loun gba ṣeṣe o, awọn akẹkọọ ẹlẹgbẹ oun ni wọn lu oun bii aṣọ of tori oun loun o ba wọn ṣẹgbẹ okunkun ti wọn pe oun si.
Baba ologbe naa, Ọgbẹni Oromoni, sọ pe dokita sọ foun pe ẹdọ ọmọ naa ti wu latari ẹjẹ didi to mu ko tobi si i nikun, eyi si ti mu ki ẹdọ naa daṣẹ silẹ.
Oromoni sọ pe: “Wọn fiya jẹ ọmọ mi, ọtunla (ọjọ kẹrin, oṣu kejila) layẹyẹ ọjọọbi ẹ iba waye, ọdọọdun ni mo maa n ṣe keeki ọjọọbi fun un. Ọmọ mi darukọ awọn ẹlẹgbẹ rẹ to lu u. Lara awọn ọmọ to darukọ wa ninu awọn ti a ti mu ẹjọ wọn lọ sọdọ awọn alaṣe ileewe naa nigba kan, nigba ti wọn fipa gba aṣọ tuntun ta a ra fun un ati ounjẹ ẹ. Ọmọbinrin meji ni mo ni, ọkan ti jade nileewe yii, mo ni lati mu ekeji kuro nigba ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ. Awọn ti wọn ṣakọlu si ọmọ mi ni ko juwe yara ti aburo rẹ wa fawọn.
Ọmọ mi sọ fun iya ẹ pe: ‘Mọmi, emi o gba bọọlu o, mi o si ṣubu kankan.’
Wọn lọmọ naa ṣalaye pe niṣe loun bẹ bọọlẹ lati ori bẹẹdi toun sun si nile tawọn n gbe, oun fẹẹ sa mọ wọn lọwọ, ṣugbọn wọn mu oun, wọn si da oun dubulẹ, wọn si bẹrẹ si fẹsẹ janlẹ lori oun, ni ibadi oun. Wọn dunkooko m’awọn akẹkọọ yooku pe ẹnikẹni to ba taṣiiri iṣẹlẹ yii ninu wọn, kele aa gbe tọhun.
Baba oloogbe naa tun sọ ninu fidio kan to fi sori ẹrọ ayelujara lọjọ Ẹti, Furaidee yii, pe: “Ọmọ mi sọ fun mi pawọn siniọ rẹ nileewe lawọn to da a loro yii, wọn rẹn ẹn mọlẹ, wọn fipa rọ kẹmika gbigbona si i lọfun.
Nigba ti wọn wọnu ile tawọn ọmọ naa n gbe, niṣe ni wọn pana, ti wọn si sọ fawọn ọmọleewe to ri wọn pe awọn maa pa wọn danu ti wọn ba lọọ ṣofofo pẹnrẹn. Awọn ni wọn sọ fun ọmọ mi pe ko purọ pe ere ori papa lawọn n ṣe, pe bọọlu lawọn n gba. Wọn halẹ mọ ọn pe to ba fi le sọ ootọ, awọn maa fiya jẹ ẹ. Tẹ ẹ ba bi awọn ti wọn jọ n gbe yara kan naa, irọ ni gbogbo wọn n pa, tori wọn ti halẹ mọ wọn. Wọn tẹ ọmọ mi mọlẹ, wọn fẹsẹ jan an laya ati nibadi leralera, bi wọn ṣe n lọ lori ẹ ni wọn n bọ. Ẹ wo inira nla ati iya buruku ti wọn fi jẹ ọmọ ọdun mejila pere.’
Bẹẹ ni baba oloogbe naa daro ọmọ rẹ, Sylvester.’