Nitori bawọn tọọgi ṣe n kina bọ ọfiisi awọn alaga kansu, Tinubu paṣẹ eto aabo ni Rivers 

Adewale Adeoye

Owe awọn agba kan to sọ pe agba ki i wa lọja kori ọmọ tuntun wọ lo ṣe rẹgi pẹlu igbesẹ gidi ti olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, gbe nipa bo ṣe paṣẹ fun ọga ọlọpaa patapata lorileede yii pe ko da awọn ọmọọṣẹ rẹ sita lọpọ yanturu lati lọọ pese aabo fawọn araalu nipinle Rivers, paapaa ju lọ nigba to ti foju han gbangba pe esi ibo sipo alaga kansu to waye nipinlẹ naa laipẹ yii ko tẹ awọn kan lọrun rara, ti wọn si ti fẹẹ sọrọ naa di ogun abẹlẹ nipinlẹ naa bayii.

O fẹẹ jẹ pe latigba ti alaga ajọ eleto idibo nipinlẹ Rivers, iyẹn ‘Rivers Independent Electoral Commission (RSEIC) Justice Adolphus Enebeli, ti kede pe ẹgbẹ oṣelu APP ti gomina ipinlẹ naa, Ogbẹni Fubara, fara mọ ti jawe olubori ninu ibo sipo alaga kansu ipinlẹ naa ni laaṣigbo nla ti bẹ silẹ laarin ilu naa, tawọn tọọgi si n ṣe amulo ofin latọwọ ara wọn. Ṣe ni awọn afurasi ọdaran kan n lọ kaakiri ipinlẹ naa, ti wọn si n kina bọ ọfiisi awọn alaga kansu gbogbo lati maa fi sọ fun gomina ipinlẹ naa, Ọgbẹni Fubara, pe awọn ko gba eru to ṣe lasiko ibo sipo alaga kansu ipinlẹ naa to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii wọle rara.

Oludamọran Aarẹ Tinubu nipa eto iroyin, Ọgbẹni Bayọ Ọnanuga, lo sọrọ ọhun di mimọ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, niluu Abuja, pe Aarẹ Tinubu ti paṣẹ fun ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa patapata lorileede yii pe ko da awọn ọmọọṣẹ rẹ sita lọpọ yanturu lati kapa awọn afurasi ọdaran kan ti wọn n ṣe amulo ofin lati ọwọ ara wọn nipinlẹ Rivers bayii.

Atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe, ‘‘O fẹẹ jẹ pe lati ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii, lẹyin ti wọn dibo sipo alaga kansu nipinlẹ Rivers, ni wahala ojoojumọ ti n waye laarin ilu naa. Awọn oloṣelu ipinlẹ naa kan tinu wọn ko dun si abajade esi ibo naa lo n lo awọn afurasi ọdaran kan pe ki wọn maa da wahala silẹ laarin ilu naa, wọn n kina bọ ọfiisi awọn alaga kansu gbogbo, eyi ko daa to rara. Inu Aarẹ Tinubu ko si dun si eyi.

Aarẹ Tinubu waa rọ awọn oloṣelu ipinlẹ naa tinu n bi pe ki wọn so ewe agbejẹẹ mọ’wọ lori ọrọ naa, ki wọn si bawọn ọmọlẹyin wọn sọrọ ni kia nipa iṣẹlẹ ọhun. Bakan naa ni olori orileede yii tun paṣẹ fun ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa pe ko da awọn ọmọọṣẹ rẹ sita lọpọ yanturu lati kapa awọn afurasi ọdaran ti wọn n ṣe amulo ofin latọwọ ara wọn yii, ko si pese aabo fawọn araalu ipinlẹ naa ni kia.

Ni ipari ọrọ rẹ, Tinubu ni oun ko ni i laju oun silẹ kawọn ọbayejẹ ẹda kan maa kina bọ ọfiisi awọn alaga kansu, tabi ba awọn dukia tijọba fowo nla ṣe jẹ.

Bẹ o ba gbagbe, ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni idibo sipo alaga kansu waye nipinlẹ Rivers, ti ẹgbẹ oṣelu APP, iyẹn ẹgbẹ oṣelu tuntun kan ti gomina ipinlẹ naa, Ọgbẹni Fubara, fọwọ si jawe olubori, ijọba ibilẹ mejilelogun ninu mẹtalelogun ti wọn ti dibo ni ẹgbẹ rẹ ti wọle. Eyi si wa lara awọn ohun to n fa wahala laarin ilu naa tawọn ọmọ ganfe kan tawọn oloṣelu ipinlẹ naa n lo fi n kina bọ ọfiisi awọn alaga kansu gbogbo bayii.

Leave a Reply