Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, lawọn onibaara ileefowopamọ UBA, ya bo Opopona Ibrahim Taiwo, niluu Ilọrin, ni ẹka ọfiisi banki ọhun, ti wọn si fẹhonu han lori bi wọn ṣe n ja owo wọn nijakujaa.
Ọkan lara awọn olufẹhonu han naa to ba awọn oniroyin sọrọ, Sideeq Fọrlarin, sọ pe nnkan naa ti kọja afarada pẹlu bi banki naa ṣe kan n ja owo oun bo ṣe wu wọn. O ni ẹgbẹrun lọna ogun naira lo wọle si inu akanti oun, ti ẹgbẹrun lọna ogun naira si wa nibẹ tẹlẹ, ti apapọ rẹ si jẹ ẹgbẹrun lọna ogoji naira, ṣugbọn ṣe ni wọn yọ ẹgbẹrun lọna mẹẹẹdogun naira lai ru, lai sọ, kọda ọna ti owo naa gba kuro ninu akanti ko ye oun rara.
Ẹlomiiran to tun ba awọn oniroyin sọrọ, Ademola Ibrahim, sọ pe ẹgbẹrun lọna mẹrinlelogun naira loun ni ni akanti koun too lọ sidii POS lagbegbe kan n’Ilọrin, lopin ọsẹ to kọja. O loun gba ẹgbẹrun lọna mọkandinlogun Naira, ti owo si ku ẹgbẹrun marun-un ninu akanti, ṣugbọn ṣe ni ileefowopamọ ọhun fi atẹjiṣẹ sọwọ pe oun ti jẹ gbese ẹgbẹrun mẹwaa din nigba naira, fun idi eyi, ki wọn da owo naa pada.
Julius Amaniga naa ṣalaye lẹkun-unrẹrẹ lori bi ileefowopamọ UBA ṣe n ṣe owo ẹ mọkumọku, o ni oun gba ẹgbẹrun mejila naira lati POS kan niluu Ilọrin, ṣugbọn oun ko ri atẹjiṣẹ kankan pe wọn yọ owo ni akanti naa lọjọ Aiku, Sannde, ti oun gba a.
Julius ni owurọ kutu ọjọ Aje, ni nnkan bii aago mẹfa idaji, loun ri atẹjiṣẹ ti wọn kọkọ yọ ẹgbẹrun mẹwaa le ni igba naira, ko pẹ ni wọn tun yọ ẹgbẹrun mẹta naira ni akanti naa, loun ba sare ko owo to ku kuro ninu asunwọn ikowosi yii.
Tẹ o ba gbagbe, ileefowopamọ agba ilẹ yii, CBN, ti sọ nibẹrẹ ọdun yii pe eyikeyii ileefowopamọ ti wọn ba ja owo onibaara nijakujaa, ki wọn maa fi iwe ẹsun sọwọ. Eyi lo fa a tawọn olufẹhonu han naa ṣe gba ileefowopamọ UBA lọ lati lọọ fẹsun kan wọn.