Nitori bi wọn ṣe pa awọn kan ninu wọn, ẹgbẹ Onigbagbọ ṣewọde l’Ọwọ

Jọkẹ Amọri
Ẹgbẹ awọn Onigbagbọ niluu Ọwọ ti ṣe ifẹhonu han lori akọlu to waye ninu ijọ St Francis to wa niluu naa lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nibi ti wọn ti pa ọpọlọpọ eeyan, tawọn mi-in si fara pa yannayanna.
Aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn eeyan naa jade pẹlu akọle loriṣiiriṣii lati fi aidunnu wọn han si iṣẹlẹ naa, ti wọn si n rọ ijọba apapọ lati wa nnkan ṣe si i.
Lara awọn ohun ti wọn kọ si awọn paali ti wọn gbe lọwọ ni, ‘Ẹ yee gbogun ti awa Onigbagbọ’, ‘Awọn Onigbagbọ nilo idajọ ododo’, ‘A o fẹ kẹ ẹ waa maa ki wa niki ibanujẹ mọ, ẹ gbe igbesẹ to yẹ, ‘Ẹ yee fi aye wa ṣe oṣelu’ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni awọn afẹmiṣofo kan kọ lu ijọ Katoliiki to wa niluu Ọwọ, ti wọn si pa eeyan rẹpẹtẹ nibẹ.

Leave a Reply