Adewale Adeoye
Afi ba a ba fẹẹ parọ tan ara wa nikan lo ku o, ilu le, eyi gan-an lo fa a tijọba apapọ ṣe sọ pe ko ni i si ariya tabi ajọyọ kan rẹpẹtẹ lasiko ayajọ ajọdun ominira orileede yii to maa waye laipẹ yii. Eyi si ni igba keji tijọba maa ṣe bẹẹ latigba ti wọn ti gba iṣakooso ijọba orileede lọwọ awọn to gbe e silẹ fun wọn.
Akọwe agba ijọba apapọ, Sẹnetọ George Akume, lo sọrọ ọhun di mimọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ ketadinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ l’Abuja.
Akume ni, ‘‘Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, atawọn to n ba a ṣiṣẹ mọ pe ilu le, ọpọ ọmọ orileede yii lo n koju oke iṣoro kan tabi omiran. Idi niyi tijọba ṣe fagi le ayẹyẹ ọdun ti orileede yii gbominira lọwọ awọn oyinbo Gẹẹsi, wọn ko ni i ṣayẹyẹ naa ni alariwo rara. Wọọrọwọ la maa ṣe e nile ijọba, l’Abuja.
‘’Aarẹ Tinubu ba awọn ọmọ orileede yii kedun ohun ti wọn n la kọja lọwọ yii. Tinubu mọ daju pe nnkan ko fara rọ fawọn araalu, paapaa ju lọ nipa ọrọ-aje, agbara kaka lawọn eeyan fi n ri ounjẹ jẹ bayii. Idi ree ti Aarẹ fi paṣẹ pe ki wọn ṣayẹyẹ ajọdun ominira naa ni wọọrọwọ ni, ko gbọdọ si wẹjẹ-wẹmu kankan gẹgẹ bo ti ṣe maa n waye tẹlẹ. Bo ṣe ri niyi lọdun to kọja ti orileede yii n ṣayẹyẹ ọdun kẹtalelọgọta. Wọn ko fiwe pe awọn olori orileede kankan lati ilẹ okeere lati waa ba wa ṣẹyẹ ọdun ominira ilẹ wa’’.
Akume ni gbogbo ohun tawọn araalu n koju lasiko yii waye nipasẹ awọn igbesẹ kọọkan ti ijọba apapọ gbe latigba to ti gbajọba. Lara rẹ ni yiyọwo iranwọ lori epo bẹntiroolu, o ni eyi ṣe pataki pupọ nitori pe laipẹ yii lawọn araalu yoo maa janfaani rẹ.
Bakan naa lo ni ijọba apapọ n ṣe awọn eto kan lọwọ bayii ti yoo mu idẹrun ati itura ba awọn ọmọ orileede yii laipẹ ọjọ.