Stephen Ajagbe, Ilorin
Ero inu kẹkẹ Maruwa mẹta lo pade iku ojiji lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, nigba ti tirela kan lọọ kọ lu wọn lagbegbe Oke-Oyi, niluu Ilọrin.
ALAROYE gbọ pe ṣe lawọn ọdọ kan ya bo tirela naa, ti wọn si kana lu u to jona gburugburu.
Gẹgẹ bi alaye tawọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn se, dẹrẹba to wa kẹkẹ Maruwa naa ṣadeede ya wọnu ile-epo bẹntiroolu lati ra epo, lai mọ pe ọkọ tirela naa n ba ere buruku bọ.
Wọn ni ki onikẹkẹ naa too mọ ohun to n ṣẹlẹ, tirela ọhun ti kan wọn lara tan, ṣe lo run wọn mọnu kẹkẹ naa ko too di pe o raaye duro.
Lawọn ọdọ ba ya bo awakọ tirela naa, wọn si lu u lalubami titi tẹjẹ fi bẹ jade lara rẹ. Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa to tete de sibi iṣẹlẹ naa lati gba a silẹ ni ko jẹ ki wọn gbẹmi rẹ.
Awọn ọdọ to n binu naa ko duro lori jijo tirela naa nikan, ṣe ni wọn tun bẹrẹ si i kọ lu ọkọ akẹru ti wọn ba ti ri nikọja.