Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ile-ẹjọ Majisreeti kan to fi ilu Ilọrin ṣe ibujokoo ti paṣẹ pe ki wọn sọ Fulani kan, Alaaji Haruna Adu, si ọgba ẹwọn Oke-Kura, niluu Ilọrin, fẹsun pe o ṣa Jamiu Sọliu to n ta burẹdi ladaa pa niluu Kanbi, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ naa, nitori burẹdi ọgọrun-un Naira.
ALAROYE gbọ pe ẹgbọn oloogbe naa ti wọn ko darukọ lo mu ẹsun lọ si ileeṣẹ ọlọpaa ẹka tipinlẹ Kwara, pe Fulani kan, Alaaji Haruna, ṣeku pa aburo rẹ, Jamiu, ni ilu Kanbi, eyi lo mu ki awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii, ti wọn si gba afurasi ọdaran naa mu.
Agbefọba Insipẹkitọ Innocent Owoọla, sọ fun ile-ẹjọ pe lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji, ọdun 2022, ni afurasi naa ra burẹdi lọwọ Jamiu, ti ọrọ owo si da ede aiyede silẹ laarin wọn, ni Haruna ba mu ada ọwọ rẹ, o si ṣa Jamiu oniburẹdi pa titi to fi ku.
Onidaajọ Abdulganiyu Ajia paṣẹ pe ki wọn lọọ fi Alaaji Haruna si ọgba ẹwọn Oke-Kura, niluu Ilọrin. Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹfa, ọdun yii.