Nitori burẹdi, ọkunrin kan luyawo ẹ pa l’Ekoo

Monisọla Saka

Ọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Enugu kan, Ndubisi Nwadiegwu, ti lu iyawo ẹ, Ogochukwu Enene, pa nitori burẹdi. Oloogbe ni wọn lo wa lati abule Umuokpu, Awka, nipinlẹ Anambra, ṣugbọn to lọọ lọkọ nipinlẹ Enugu.

ALAROYE gbọ pe akọbi oloogbe lọkunrin, ọmọ ọdun mẹrinla, ni wọn lo ṣalaye bọrọ naa ṣe  ṣelẹ pe, gilaasi ti wọn fi n woju ni baba awọn fi luya awọn pa, nitori pe iya awọn sọ pe ko ra burẹdi fawọn ọmọ, ti baba si loun ko lowo lọwọ.

O ni lẹyin ti baba awọn ko ṣeto bawọn ṣe maa jẹun lọjọ naa ni mama awọn lọọ fowo ọwọ ara ẹ ra burẹdi fawọn. Ṣugbọn baba awọn ko ṣe meni ṣe meji, o gba inu kinṣinni lọ nibi ti iya awọn gbe burẹdi si ko too wọle lọ, to si pari gbogbo burẹdi naa pata. O ni nigba ti mama awọn beere idi ti baba awọn fi jẹ burẹdi toun ra fawọn ọmọ, ni ọkunrin naa fa ibinu yọ, to bẹrẹ si i lu iya awọn titi to fi jẹ Ọlọrun nipe.

Bo tilẹ jẹ pe awọn mọlẹbi oloogbe ko ti i sọ nnkan kan lori iṣẹlẹ naa, ẹnikan to sun mọ ẹbi naa sọ fun iwe iroyin Punch pe ipinlẹ Eko niṣẹlẹ naa ti waye.

O ni,”Ọmọ marun-un ni Ọlọrun jogun fun obinrin yii, ọmọkunrin mẹrin ati obinrin kan. Akọbi ẹ lọkunrin to jẹ ọmọ ọdun mẹrinla sọ pe lẹyin ti mama awọn fowo ara ẹ ra burẹdi tan ni baba awọn wọnu kinṣinni lọ, to si pari gbogbo burẹdi to yẹ kawọn ọmọ jẹ. Nigba toloogbe waa beere pe ki lo de to jẹ burẹdi lai ṣẹ nnkan kan ku fawọn ọmọ, lo bẹrẹ si i lu u titi to fi lu u pa”.

Leave a Reply