Nitori ẹbọ ti wọn ba lorita ilu wọn, idaamu nla ba awọn eeyan Ọwẹna, wọn ni ami buruku ni

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Inu ibẹrubojo lawọn eeyan ilu Ayetoro-Ọwẹna, ti i ṣe ibujokoo ijọba ibilẹ Idanre, wa latari ẹbọ nla kan ti wọn deedee ba ni orita ilu ọhun laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un, yii.

Gẹgẹ bi akọroyin ALAROYE paapaa ṣe foju ara rẹ ri i lasiko ta a ṣabẹwo siluu ọhun, odidi oodi ẹyin nla to ti pọn kan lawọn eeyan ọhun fi aṣọ funfun we, ti wọn si lọọ foru gbe e si ikorita to wọ ilu.

Ọkan ninu awọn agba ilu ọhun to kọkọ ba wa sọrọ, ṣugbọn to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ni ki i ṣe igba akọkọ ree ti iru iṣẹlẹ bẹẹ yoo waye lagbegbe naa.

O ni oun ti awọn ṣakiyesi ni pe igbakugba ti nnkan rere kan ba ti fẹẹ wọ ilu ni iru nnkan bẹẹ maa n waye.

O ni loootọ ni Ayetoro-Ọwẹna jẹ ibujokoo ijọba ibilẹ Idanre, ṣugbọn ko si nnkan gidi kan ti awọn le tọka si pe o wa lagbegbe naa.

Baba ọhun ni odo nla kan ti wọn n pe ni Omi-Ọwẹna, lo paala laarin Ayetoro-Ọwẹna ti ijọba ibilẹ Idanre, ati Ọwẹna-Ẹyin omi to jẹ tijọba ibilẹ Ila-Oorun Ondo.

O ni bo tilẹ jẹ pe Ọwẹna-Ẹyin omi ki i ṣe ibujokoo ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ondo, sibẹ, ọpọ awọn ohun amayedẹrun bii ọja, ile-iwe alakọọbẹrẹ ati girama pẹlu ile-iwosan to n ṣiṣẹ lo wa nibẹ titi di ba a ṣe n sọrọ yii.

O ni ṣugbọn Ayetoro-Ọwẹna, nibi tawọn n gbe, lo ni o jẹ ibujokoo ijọba ibilẹ kan ṣoṣo ninu gbogbo ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo ti ko ni ile-iwe girama tirẹ pẹlu ọja ti wọn n na.

O ni ọja nla to wa ni Ọwẹna-Ẹyin omi lawọn n na, bẹẹ ni ile-iwe girama wọn lawọn ọmọ awọn n lọ.

Ọja kan ṣoṣo to wa niluu wọn lo ni o ti tu, ti wọn ko si na an mọ lati bii ọdun mẹẹẹdọgun sẹyin, ti awọn ko si ri ohunkohun ṣe si i láti igba naa.

O ni igba kan wa ti awọn gbiyanju lati si ọja yii pada, o ni tidunnu tidunnu ‘awọn eeyan fi na ọja yii lọjọ ti awọn kọkọ si i, ọjọ keji ti wọn tun na an lo ni awọn ba ẹbọ buruku kan ti wọn waa gbe si orita ilu yii, leyii to tun tu ọja ọhun, ti ko si sẹni to tun dabaa ati ṣi i pada lati igba naa.

Ileewe girama kan ṣoṣo to wa niluu Ayetoro-Ọwẹna lo ni ijọba ti ti pa lati bii ogoji ọdun sẹyin, o ni o ṣee ṣe ko jẹ igbesẹ to n lọ lọwọ lori ṣiṣi i pada lo tun ṣokunfa ẹbọ buruku tawọn oniṣẹẹbi naa tun lọọ gbe si orita ilu.

O ni ṣe ni ibẹrubojo gba ọkan awọn araalu kan latari ẹbọ buruku ti wọn gbe ọhun, nitori ko sẹni ti ko mọ pe apẹẹrẹ buruku patapata ni gbigbe odi ẹyin sibi kan gẹ́gẹ́ bíi ẹbọ.

Gbogbo akitiyan wa lati ri ọba ilu ọhun ba sọrọ lo ja si pabo, ohun ta a gbọ ni pe ilu Eko ni kabiyesi fi ṣe ibugbe, ẹkọọkan lo si maa n wa si ilu ibi to jọba si.

Ẹgbọn kabiyesi, Baba-Ọba Ọlọfintẹ Olu, to ba wa sọrọ lorukọ ilu jẹ ko ye wa pe apẹẹrẹ buburu gbaa ni iru ẹbọ ti wọn gbe naa jẹ.

O ni erongba awọn agbẹbọ naa ni pe ki ilu le tu patapata pẹlu bi ọmọ ẹyin naa ba ṣe n yọ lọkọọkan kuro lara odi rẹ.

O ni ni kete ti awọn ti ri i loun ti pe Kabiyesi lati fi iṣẹlẹ naa to o letí, lẹyin eyi lo ni awọn ranṣẹ lọ si aafin Ọwa tilu Idanre, ti awọn si sọ ohun to ṣẹlẹẹ fun wọn.

Gbogbo sọọsi ati mọṣalasi to wa laarin ilu lo lawọn ti bẹ lọwẹ pe ki wọn wọle adura, ti Ọwá si ti ran awọn Aleroro wa lati ilu Idanre, ki wọn le ṣetutu ti yoo sọ erongba awọn ọta ilọsiwaju ọhun di asan.

Ọlọfintẹ ni awọn ilu to wa nitosi Ayetoro-Ọwẹna lawọn fura si lori iṣẹlẹ ọhun, bẹẹ lo tun rọ awọn eeyan ilu lati fọkan ara wọn balẹ, ki wọn si maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ lai foya.

Leave a Reply