Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Iṣẹlẹ iku ọkunrin ẹni ọdun mejidinlọgọta kan, Bamidele Ọmọlayọ, ẹni ti wọn ṣalaabapade oku rẹ nibi ti wọn lo pa ara rẹ si niluu Ìgbúròwò, nijọba ibilẹ Odigbo, ti ko awọn eeyan agbegbe naa sinu ibẹru nla.
ALAROYE gbọ pe ẹnikan lo kọkọ ri oku ọkunrin ti wọn n pe inagijẹ rẹ ni Baba Riga ọhun nilẹ ibi to na gbalaja si lẹgbẹẹ oju ọna ti wọn n gba lọ si oko nla kan to wa nitosi ilu ọhun, ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ aarọ ọjọ yii.
Ọrọ iku Bamidele ni wọn lo kọkọ ṣoro fawọn eeyan ilu ọhun lati gbagbọ, kayeefi nla ni igbesẹ ti baale ile naa gbe ati idi to fi gbe iru igbesẹ buruku bẹẹ jẹ fun wọn.
Eyi lo ṣokunfa bi ọgọọrọ awọn araalu ọhun ṣe mori le ọna ibi ti wọn lo pa ara rẹ si lati foju gan-an-ni ohun to sẹlẹ gan-an nigba ti wọn gbọ iroyin ohun to ṣẹlẹ naa.
Ọmọ bibi ilu Ìgbúròwò ni wọn pe Bamidele, o niyawo, bẹẹ lo ti bimọ mẹrin ki ọlọjọ too de. Laipẹ yii ni wọn ni ede-aiyede kan bẹ silẹ laarin oun atawọn ẹbi rẹ, leyii to mu ki ọkunrin naa maa leri pe ṣe loun maa gbe tarí mu, ti oun yoo si pa ara oun si wọn lọrun.
Ihalẹ lasan lawọn ẹbi rẹ pe ọrọ yii, afi bi Bamidele ṣe mu ileri rẹ ṣẹ laaarọ ọjọ buruku eṣu gbomi mu yii. Koda, o ni lati rin jinna si aarin ilu daadaa ko too da majele to gbe lọwọ mu.
Awọn to lọ sibi iṣẹlẹ ọhun fidi rẹ mulẹ pe awọn ṣi ba ike tarí to gbe mu ati bata to wọ debẹ lẹgbẹẹ ibi to ku si, ti foonu apo rẹ pẹlu si n ke tantan nigba tawọn eeyan kan n pe e.
Ohun to le mu ki baba ẹni ọdun mejidinlọgọta ọhun pinnu lati gbe iru igbesẹ bẹẹ ṣi ṣokunkun sawọn eeyan. Titi ta fi pari akojọpọ iroyin yii, pabo ni gbogbo akitiyan akọroyin wa lati ri eyikeyii ninu awọn ẹbi oloogbe ọhun ba sọrọ.
Awọn ọlọpaa to wa ni Eeria kọmandi ilu Ọrẹ, ni wọn pada lọọ fi iṣẹlẹ naa to leti, awọn ni wọn si ṣeto bi wọn ṣe waa gbe oku rẹ kuro, ti wọn si lọọ tọju rẹ si mọṣuari ọsibutu ijọba to wa niluu Ọrẹ, nibi to ṣi wa lọwọlọwọ.
Ohun ta a gbọ ni pe awọn ọlọpaa ti n ranṣẹ pe awọn ẹbi Bamidele lọkọọkan lati fọrọ wa wọn lẹnu wo.
Nigba to n fìdí iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni awọn ti gbọ nipa rẹ. O fi kun un pe awọn ti bẹrẹ ẹkunrẹrẹ iwadii lori ohun to le ṣokunfa iṣẹlẹ naa.