Nitori ẹgbẹrun mẹta Naira, agbofinro binu ge ọwọ iyawo ẹ to loyun bọ silẹ

Monisọla Saka

Nitori iwa ika to hu siyawo rẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Plateau, ti sọ ọkan lara wọn satimọle.

ALAROYE gbọ pe ẹgbẹrun mẹta Naira (3,000), lo dija silẹ laarin tọkọ-taya yii, ni ọlọpaa ti wọn ko ti i darukọ rẹ yii ba fibinu ge ọwọ iyawo ẹ, lati ọrun ọwọ, titi mọ gbogbo ika rẹ lo ge bọ silẹ, nile wọn to wa lagbegbe Dong, nijọba ibilẹ Ariwa Jos, nipinlẹ Plateau.

Ninu owo ti ọkunrin naa tọju sile ni wọn ni iyawo ẹ ti yọ ẹgbẹrun mẹta, eyi ni wọn lo fa ede-aiyede laarin wọn, to fi binu sọ ọwọ iyawo ẹ kalẹ.

Ọkan lara awọn ti wọn jọ n gbe to forukọ bo ara ẹ laṣiiri sọ pe, “Inu oyun niyawo yẹn wa, nitori bo ṣe kọ lati fun ọkunrin yẹn ni ẹgbẹrun mẹta ninu ẹgbẹrun lọna ogun Naira yẹn lo di wahala. Lasiko ti wọn n fa ọrọ naa mọra wọn lọwọ, ki a too mọ ohun to n ṣẹlẹ, ọkunrin yii ti ge iyawo ẹ lọwọ bọ silẹ. Ko sẹni to mọ idi to fi ṣe bẹẹ, ṣugbọn awa ti sare gbe e lọ sile iwosan ni tiwa”.

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ naa, DSP Alfred Alabo, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ṣalaye pe awọn ti fi panpẹ ofin gbe afurasi, iwadii si ti n lọ lori iṣẹlẹ naa.

“Ede-aiyede kekere kan ni wọn lo waye laarin oun atiyawo ẹ nitori owo. Ẹgbẹrun lọna ogun Naira ti wọn ni o tọju sile, nigba to dari dele pada to ni oun n wa owo naa lati fi ṣe nnkan kan ti ko si pe iye to ko sibẹ ni ariyanjiyan bẹ silẹ laarin wọn. Ibinu pe iyawo rẹ mu ẹgbẹrun mẹta ninu owo yii lo fi huwa ti ko bofin mu to hu ọhun”.

O fi kun ọrọ ẹ pe awọn ti bẹrẹ iwadii, nitori insipẹkitọ ọlọpaa ni afurasi yii. O ni awọn ti gbe e lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn ti n wadii iwa ọdaran, iyẹn Criminal Investigation Department (CID).

Leave a Reply