Nitori ẹgbẹrun mẹtadinlọgọta Naira to ji, adajọ ti ni ki wọn lọọ yẹgi fun fọganaisa kan

Monisọla Saka

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni Onidaajọ Mojisọla Dada, ti ile ẹjọ to n ri si awọn ẹsun kan to yatọ, Special Offences Court, to wa n’Ikẹja, nipinlẹ Eko, dajọ pe ki wọn yẹgi fun ọkunrin fọganaisa ẹni ọdun mejilelọgbọn (32), Chidozie Onyinchiz, titi ti ẹmi yoo fi bọ lara ẹ, nitori ẹgbẹrun lọna mẹtadinlọgọta (57,000), to ji lọwọ nọọsi kan.

Onidaajọ Dada sọ pe olujẹjọ jẹbi awọn ẹsun mẹta kan: ilẹdi apo pọ, idigunjale ati ẹgbẹ okunkun ṣiṣe ti wọn fi kan an.

O ni gbogbo akitiyan ọdaran yii lati yọ bọrọ kuro ninu gbogbo awọn ẹsun yii lo ja si pabo.

O tẹsiwaju pe nitori ti oun ti fidi ọrọ tawọn ọlọpaa teṣan Igando, nipinlẹ Eko, mulẹ, pe obinrin to ja lole ọhun, Arabinrin Veronica Uwayzor, ri i, awọn mejeeji si da ara wọn mọ lasiko to n ṣiṣẹ ibi naa, awọn ẹri yii loun yoo fi ṣedajọ ọdaran yii.

O ni, “Agbefọba ti kọkọ ṣalaye pe olupẹjọ naka si ọdaran gẹgẹ bii ọkan ninu awọn ọkunrin meji ti wọn fi sisọọsi ati irin nla kan ja baagi oun, ti wọn si gba owo to to ẹgbẹrun lọna mẹtadinlọgọta to wa ninu ẹ ni tipatipa, lagbegbe Akẹsan, Igando, nipinlẹ Eko.

Onyinchiz to ni iṣẹ fọganaisa loun yan laayo gba pe ọkan ninu ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ loun, bẹẹ lo sọ pe igba akọkọ toun maa wa jale ni Akẹsan niyẹn.

Adajọ Ọnayinka sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Onyinchiz, ta ko ofin ọdaran ipinlẹ Eko ti ọdun 2015. O fi kun un pe awọn ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ yii fi han pe olujẹjọ jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an.

Nitori idi eyi, adajọ paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun ọdaran naa titi ti ẹmi yoo fi bọ lara ẹ. O ṣadura pe ki Ọlọrun ṣiju aanu wo o.

Leave a Reply