Adeoye Adewale
Oṣiṣẹ ajọ Imigireṣan kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Lamba, ti yinbọn Oloogbe Jacob Bamgbọla, nitori ẹgunjẹ igba Naira to fẹẹ gba lọwọ rẹ ni Ijoun, nitosi Idiroko, nipinlẹ Ogun.
ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ aburu ọhun waye lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Keje, ọdun yii, nigba ti Jacob n gbe ọmọ ẹgbọn rẹ obinrin kan pada sile awọn obi rẹ pẹlu ọkada rẹ lagbegbe Ijowun, lọna Idiroko.
Bo ṣe de ibi tawọn Imigireṣan naa wa ni ọkan lara awọn to n gba ẹgunjẹ lọwọ awọn to n kọja loju titi naa ti beere owo lọwọ Jacob, ṣugbọn to ta ku pe oun ko ni i fun wọn. O ṣalaye fun wọn pe ọmọ agbegbe naa loun. Ẹnu ọrọ yii ni wọn wa ti wọn fi fi Jacob silẹ lori iduro, ti wọn tun fi lọọ ba awọn mi-in lati gba owo lọwọ wọn.
Bi Jacob si ṣe ri i pe ko sẹnikankan lọdọ oun mọ lo ba sa lọ, to si gbe ọmọ ọhun fawọn obi rẹ. Lẹyin naa lo lọọ sọ ohun toju rẹ ri lọwọ awọn aṣọbode yii fawọn ọdọ agbegbe naa. Nitori pe awọn kọọkan lara awọn ọdọ ti Jacob n fẹjọ sun paapaa ti koju irufẹ iṣoro bẹẹ lọwọ awọn agbofinro gbogbo ti wọn maa n yọ wọn lẹnu ni gbogbo wọn ṣe fimọ ṣọkan lati lọọ fọrọ ọhun to baalẹ ilu naa, Oloye Moses Falẹyẹ, leti. Ṣe ni wọn n kọrin ogun pẹlu ọtẹ de agbala baalẹ naa. Ẹnu alaye ohun ti wọn n koju lọwọ awọn agbofinro gbogbo, paapaa ju lọ awọn aṣọbode ti wọn wa lagbegbe naa ni wọn wa, tawọn Imigireṣan ọhun tun fi ya de saafin baalẹ naa. Gbau-gbau ni wọn n yinbọn ọwọ wọn soke, ti wọn ko si gbọ alaye ti baalẹ naa n gbiyanju lati ṣe fun wọn. Ọkan lara ọta ibọn ti wọn n yin naa lo ba Jacob.
Loju-ẹsẹ lo si ti ṣubu lulẹ gbalaja. Ẹsẹkẹsẹ naa lawọn ẹlẹgbẹ rẹ yooku ti gbe e lọ si ọsibitu aladaani kan to wa laduugbo ọhun, ṣugbọn gbara ti wọn gbe Jacob debẹ lawọn dokita ti wọn ba lẹnu iṣẹ sọ pe oku Jacob ni wọn gbe wa sọdọ awọn.
Lori iṣẹlẹ yii kan naa, olori ikọ awọn ọdẹ agbegbe naa, Ọgbẹni Adeṣina Alabi bu ẹnu atẹ lu bawọn ẹṣọ alaabo gbogbo lagbegbe naa ṣe maa n dena de awọn araalu naa, ti wọn si maa n gbowo lọwọ wọn nigba gbogbo.
Baalẹ ilu naa, Oloye Falẹyẹ paapaa fi aidun rẹ han si bawọn oṣiṣẹ Imigireṣan ṣe yinbọn pa Jacob.
O ni oun ti n gbiyanju lati pana wahala ọhun mọlẹ ko too di pe aṣọbode ọhun de, ti wọn si da wahala nla silẹ, eyi to ṣeku pa ọmọkunrin yii.
Agọ ọlọpaa to wa ni agbegbe Igbokofi, niluu Ọtun, nijọba ibilẹ Yewa North, nipinlẹ Ogun, ni ọn mu ẹjọ naa lọ.
Alukoro ajọ yii nipinlẹ Ogun, Ọlajide Oṣifẹsọ loun ti gbọ si iṣẹlẹ naa, awọn si ti bẹrẹ iwadii lori rẹ, tawọn si maa jabọ fawọn alaṣẹ ijọba. Bẹẹ lo ni awọn yoo jẹ ki araalu mọ abajade esi iwadii awọn lori ọrọ ọhun laipẹ yii.