Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ti o ba fẹẹ jẹ òsoko, jẹ òsoko, ti o ba fẹẹ jẹ ọ̀sáká, jẹ ọ̀sáká, èwo ni òsoko-sáká, eyi ni ọrọ to jade lẹnu ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC), ni Kwara, si Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Aarin-Gbungbun, ipinlẹ naa, nileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja, Ibrahim Yahaya Olóríẹgbẹ́ ati arakunrin kan, Alaaji Waheed Piri, ti wọn fẹsun kan pe wọn n ṣoju meji ninu ẹgbẹ, ti wọn si ṣiṣẹ ta ko ẹgbẹ oṣelu APC, nibi eto idibo gomina ati tileegbimọ aṣofin to kọja yii, ni wọn ba jawee gbele-ẹ fun wọn.
Ninu iwe kan ti ẹgbẹ oṣelu APC ni Wọọdu Ogidi, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ilọrin, (West), Ilọrin, kọ, ti Alaga wọn, Babatunde Ọlọhunoṣebi, ati Akọwe ẹgbẹ Jamiu Fatai, buwọ lu ni Tọsidee, ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹta yii, ni wọn ti kede lorukọ gbogbo ẹgbẹ naa nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ilọrin, pe awọn ti jawee gbele-ẹ fun Sẹnetọ Ibrahim Yahaya Olóríẹgbẹ́ ati Waheed Piri, fẹsun pe wọn n ṣe oju meji pẹlu ẹgbẹ naa pẹlu bi wọn ṣẹ n ṣe ẹsẹ-kan-ile ẹsẹ-kan-ode pẹlu ẹgbẹ oṣelu alatako.
Tẹ o ba gbagbe, lati igba ti Ṣẹnetọ Olóríẹgbẹ́, ti padanu tikẹẹti lati pada si sileegbimọ aṣofin agba lẹẹkeji sọwọ sẹnetọ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Saliu Mustafa, ni Olóríẹgbẹ́, ti n ṣiṣẹ ta ko ẹgbẹ, to si ṣe agbekalẹ akanṣe adura kan, leyii to fiwe pe gbogbo awọn ẹgbẹ alatako ni Kwara, bii ẹgbẹ PDP, SDP, NNPP, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Nibẹ ni Olóríẹgbẹ́ ti sọko ọrọ si Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, nibi eto adura naa. Olóríẹgbẹ́ ni oun ko ni i ṣatilẹyin fun gomina ni saa keji, Bọla Ahmed Tinubu to n dupo aarẹ ninu ẹgbẹ APC nikan loun yoo ṣatilẹyin fun, tori pe gomina ni ko jẹ ki tikẹẹti lati pada sileegbimọ aṣofin lẹẹkeji ja mọ oun lọwọ. Idi niyi to fi n ṣiṣẹ ta ko gomina Abdulraman AbdulRazaq.
Igbẹsẹ Olóríẹgbẹ ati Alaaji Waheed yii ni ALAROYE gbọ pe o fa a ti awọn oloye ẹgbẹ ni Wọọdu Ogidi, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ilọrin, naa fi jawee gbele-ẹ fun wọn pe ki wọn lọọ rọọkun ninu ẹgbẹ naa fungba diẹ naa.
Titi ta a fi pari iroyin yii, ko seyii to ti i fesi kankan ninu awọn ti wọn fun niwee ọhun.