Nitori ẹsun agbere, igbeyawo ogun ọdun tu ka l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Oluwa mi, alagbere paraku lọkọ ti mo fẹ, koda, ọjọ pẹ to ti gboye ijinlẹ ninu iwa iṣekuṣe, ẹbẹ mi ni pe kẹ ẹ tu igbeyawo ogun ọdun to wa laarin awa mejeeji ka, ko too fiwa agbere rẹ ran mi sọrun ọsan gangan.

Eyi lawọn ọrọ to n jade lẹnu obinrin oniṣowo kan, Abilekọ Ṣeun Adekanye, lasiko to mu ẹjọ ọkọ rẹ, Dada Adekanye, wa si kootu kọkọ-kọkọ to wa lagbegbe Oke-Ẹda, niluu Akurẹ.

O ni ọkunrin naa ki i bọwọ foun bii iyawo ile rẹ pẹlu ọkan-o-jọkan obinrin to n ko wale, to si n ba wọn lo pọ lori bẹẹdi ti awọn jọ n sun.

Obinrin ẹni ọdun mẹtalelogoji ọhun ni ọpọ igba lọkọ oun maa n lu oun lalubami tí yoo si tun ko awọn ẹru oun jade nitori awọn ale rẹ.

O ni gbogbo iya wọnyi loun ro papọ ti oun fi pinnu ati waa ja iwe ikosilẹ fun un nile-ẹjọ ko too fi lilu gbẹmi oun.

Ninu awijare tìrẹ, Ọgbẹni Dada ni iyawo oun ki i ṣe ọmọluabi eeyan rárá pẹlu irinkurin to n rin nitori pe igba to ba wu u lo n jade, igba to ba si fẹ lo n pada wọle.

Baba ẹni aadọta ọdun naa ni asiko kan wa ti oun ri atẹjisẹ kan ti olupẹjọ fi ransẹ sì ọkan ninu awọn ale to n ko kiri.

O ni funra rẹ lo ko ẹru rẹ kuro nile oun, to si da gbogbo ọmọ tí awọn bí si oun nikan laya lai boju wẹyin waa wo wọn.

Ọkunrin oniṣowo ẹja ọhun ni oun naa fara mọ-ọn kí ile-ẹjọ tu ibaṣepọ ọlọjọ pipẹ to wa laarin awọn ka, ki wọn si gba oun laaye lati maa tọju awọn ọmọ ti wọn bí.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Ọgbẹni Anthony Bọboye to jẹ Aarẹ kootu ọhun ni oun tú igbeyawo naa ka, kí olukuluku wọn maa ba tirẹ lọ.

Ile-ẹjọ naa fọwọ si i kí awọn ọmọ wa lọdọ olujẹjọ, kí wọn le ri itọju to peye gba.

 

 

Leave a Reply