Adewumi Adegoke
Ile-ẹjọ giga kan niluu Ado Ekiti, nipinlẹ Ekiti, ti paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun awọn ọrẹ meji kan, Deji Owoyẹmi, ẹni ọgbọn ọdun ati Ọpẹyẹmi Oluwakọmọlafẹ, ẹni ọdun mejilelogun titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn. Ẹsun idigunjale ati fifipa ba ni lo pọ ni wọn fi kan awọn eeyan naa.
Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla yii, ni Onidaajọ Monisọla Abọdunde paṣẹ naa. Agbefọba, Ilesanmi Adelusi, sọ ni kootu pe awọn afurasi ọdaran mejeeji ti ṣẹ ẹṣẹ kan tẹlẹ, eyi to sọ wọn dero ọgba ẹwọn. Ṣugbọn awọn ọdaran mejeeji yii sa lẹwọn lọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila, ọdun 2014.
Lẹyin ti wọn sa lẹwọn yii ni wọn lọọ digun ja mọlẹbi kan lole ni Ilemọba Ekiti, lọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun 2015. Lẹyin ti wọn ja wọn lole tan ni wọn tun fipa ba iyawo ọkunrin naa to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji lo pọ. Ṣugbọn ọwọ pada tẹ wọn.
Nigba to n fidi ẹsun yii muklẹ, awọn ẹlẹrii marun-un ni agbefọba naa pe, o si tun mu ibọn ilewọ ponpo kan, foonu mẹwaa, ada atawọn nnkan mi-in wa si kootu gẹgẹ bii ẹri.
Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Monisọla Abọdunde sọ pe ninu gbogbo ẹri ti awọn olufisun ko wa si kootu, o fi han pe ọdaran ati opurọ paraku ni awọn ọrẹ meji yii. O ni ohun to buru gbaa ni bi awọn mejeeji ṣe sa lẹwọn, ti wọn si tun waa n daamu awọn araalu titi ti ọwọ fi tẹ wọn.
O ni awọn ọdaran mejeeji yii jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn. Fun idi eyi, ki wọn lọọ yẹgi fun awọn mejeeji titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn.