Monisọla Saka
Ile-ẹjọ Majisireeti kan to fikalẹ sipinlẹ Kano, ti ju Alhassan Ado Doguwa, ti i ṣe olori awọn ọmọ ẹgbẹ to pọ ju lọ nileegbimọ aṣoju ṣofin sọgba ẹwọn. Lẹyin ti wọn ka ẹsun oniga marun-un kan si i lẹsẹ, eyi to da lori ipawọ-pọ huwa ọdaran, ipaniyan, lilo ibọn lọna aitọ, ati dida adugbo ru kan an l’Adajọ Majisireeti ọhun, Ibrahim Mansur Yola, ni ki wọn maa gbe e lọ si keremọnje titi di ọjọ keje, oṣu Kẹta yii, nigba ti igbẹjọ yoo tun bẹrẹ pada.
Alhassan Doguwa ni wọn fẹsun kan pe o lẹdi apo pọ pẹlu ọkunrin kan to n jẹ Bashir Dahiru, atawọn marun-un mi-in, ti wọn ti sa lọ bayii, lati da ilu ru nijọba ibilẹ Tudun-Wada, nipinlẹ Kano, lasiko ti wọn sọ ina sile ẹgbẹ oṣelu NNPP, eyi to yọri si iku ọkunrin kan to n jẹ Alhassan Sarki Pawa ati Aminu Malam.
Ija to bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ati NNPP nipinlẹ naa latari esi idibo ti wọn n kede, lo mu ki Doguwa gba ibẹ lọ, to si bẹrẹ wahala lati ta ko esi idibo ti wọn fagi le lagbegbe naa. Eyi lo ṣokunfa bi wọn ṣe pa eeyan mẹta, ti wọn si tun jo ile ẹgbẹ naa.
Agbẹjọro fun olujẹjọ, Abdul Adamu, rọ ile-ẹjọ lati faaye beeli silẹ fun onibaara oun, o ni eeyan ti wọn mọ lawujọ ni, ati pe ko ni i tori ẹ na papa bora tabi di iwadii awọn ọlọpaa lọwọ, bẹẹ loun yoo pese awọn nnkan to ṣe pataki lati duro fun un.
Agbẹjọro ijọba ni tiẹ, Aisha Salisu, ta ko aaye beeli ti ẹlẹgbẹ ẹ ni ki wọn fun afurasi, o ni ki wọn ma gba a laaye nitori ẹsun nla kan wa lara eyi ti wọn fi kan an.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kano, Muhammad Yakubu, to wọ aṣofin ọhun lọ si kootu ṣalaye pe, wahala to bẹ silẹ ati ibi idibo, ti Doguwa fi dana sun ile ẹgbẹ NNPP, lagbegbe ijọba ibilẹ Tudun-Wada, nipinlẹ Kano, eyi to ṣokunfa iku awọn mẹta kan, tawọn mẹjọ mi-in si fara pa yannayanna lasiko eto idibo ti wọn ṣẹṣẹ di lọ yii lo mu kawọn fi panpẹ ofin gbe ọkunrin naa.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Abdullahi Haruna, gbe jade lorukọ ọga rẹ lo ti sọ pe, “Iroyin kan tẹ wa lọwọ lori awọn eeyan mẹta kan ti wọn da ẹmi wọn legbodo, to tun ṣokunfa bi awọn eeyan mẹjọ kan ṣe fara pa yannayanna nijọba ibilẹ Tudun-Wada, lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, lasiko ti wọn n ka esi idibo lọwọ. Lasiko naa ni fọnran kan gba ori ẹrọ ayelujara kan, nibi tawọn eeyan kan ti fi ara gba ọta ibọn, tawọn mi-in si n yinbọn ninu fidio ọhun. Eyi lo mu ki kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kano to wa nidii kokaari eto idibo ọdun 2023, Muhammad Yakubu, paṣẹ pe ki ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣewadii iwa ọdaran (SCID), bẹrẹ iwadii lori ọrọ naa.
“Lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, lasiko ti iwadii naa ṣi n lọ lọwọ, ni ẹka to n wadii iwa ọdaran ọhun ranṣẹ pe Alhassan Ado Garba Doguwa, to jẹ ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin to n ṣoju ẹkun Doguwa/Tudun-Wada niluu Abuja, fun bo ṣe lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.
Bi Doguwa ṣe kọ lati yọju sile iṣẹ ọlọpaa, lo mu ki awọn agbofinro gbe igbesẹ lati fofin gbe e. Ninu papakọ ofurufu Aminu Kano International Airport, lawọn ọlọpaa ti wọn n ṣewadii iwa ọdaran – SCID, to wa lagbegbe Bompai, nipinlẹ Kano, ti nawọ gan an”.
Doguwa to n dije lati tun wọle sipo aṣoju-ṣofin lagbegbe ẹ lẹẹkan si i, ni wọn tun ka ibọn mọ lọwọ, ibọn yii ni wọn lo yin pa ọkunrin kan, tawọn mẹta mi-in si fara gbọgbẹ.