Nitori ẹsun jibiti, adajọ sọ ayederu sọja sẹwọn ọdun kan n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọṣẹ yii, nile-ẹjọ giga kan niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, sọ Abdulsalam Oyeyẹmi sẹwọn ọdun kan. Ẹsun pe o n parọ pe oun ṣiṣẹ ni ileeṣẹ ọmọ ologun ilẹ Amẹrika, to si fi n lu awọn eniyan ni jibiti ni wọn tori ẹ sọ ọ sẹwọn.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku EFCC, wọ Oyeyẹmi lọ siwaju     Onidaajọ Mahmood Abdulgafar, fẹsun pe o n pe ara rẹ ni a.k.a Colt Williams, James Anderson, ninu oṣu kẹta, ọdun to kọja, to si fi lu arabinrin oyinbo kan to n jẹ Cristina Gobin (a.k.a Cristina Haripaul), ni jibiti. O sọ fun obinrin naa pe oun ni James Anderson, ọmọ ileeṣẹ ologun ilẹ Amerika, oun jẹ oluransẹ ọkọ rẹ Colt Williams, to si n ba a sakoso ayelujara rẹ. Arabinrin naa fi ẹgbẹrun kan le ni igba dọla owo ilẹ Canada sọwọ si Oyeyẹmi. Adebayọ Aliyu to jẹ asoju ajọ EFCC lo ko gbogbo ẹri siwaju ile-ẹjọ lati fidi otitọ mulẹ.

Olujẹjọ naa gba pe loootọ lo jẹbi ẹsun ti ajọ naa fi kan an.

Nigba ti Onidaajọ Abdulgafar n gbe idajọ rẹ kalẹ, o ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii ati awọn ẹri ti olupẹjọ ko siwaju ile-ẹjọ, o han pe loootọ ni olujẹjọ naa jẹbi ẹsun jibiti ti wọn fi kan an, fun idi eyi, ki Oyeyẹmi lọọ ṣẹwọn ọdun kan ni ọgba ẹwọn Mandala, niluu Ilọrin, bakan naa ladajọ tun ni ki gbogbo awọn dukia to ko jọ lọna eru di tijọba apapọ ati owo ti wọn ba lọwọ rẹ, ẹgbẹrun lọna igba naira ko di tijọba.

Leave a Reply