Nitori ẹsun jibiti lori ẹrọ ayelujara, adajọ sọ ọmọ ‘yahoo’ sẹwọn oṣu mẹfa ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla yii, ni ile-ẹjọ giga kan to filu Ilọrin ṣe ibujokoo ti ni ki gende-kunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Yusuf Ọlarewaju, lọọ fi ẹwọn oṣu mẹfa jura tabi ko san ẹgbẹrun lọna igba Naira (#200,000) gẹgẹ bii owo itanran lori ẹsun lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara.

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọku-mọku nilẹ yii, EFCC, ẹka tilu Ilọrin, lo mu Ọlarewaju niluu Ẹrin-Ile, nijọba ibilẹ Ọyun, nipinlẹ Kwara, pe o n lu jibiti lori ayelujara ni ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, eyi lo mu ki wọn wọ ọ lọ si kootu, ti wọn si ko awọn ẹri maa jẹ mi niṣo siwaju adajọ.

Ọlarewaju gba pe loootọ loun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Adajọ Adebayọ Yusuf, paṣẹ ki Ọlarewaju lọọ faṣọ penpe roko ọba fun oṣu mẹfa tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun lọna igba Naira (200,000), ki gbogbo dukia ti wọn ba lọwọ rẹ ati owo di ti ijọba apapọ.

Leave a Reply