Nitori ẹsun jibiti ori ẹrọ ayelujara, adajọ sọ agunbanirọ sẹwọn ọdun meji ni Kwara

Ile-ẹjọ giga kan niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti sọ agunbanirọ kan, Christopher Adetuberu, sẹwọn ọdun meji lori ẹsun lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara.

 

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ nilẹ yii, EFCC, lo wọ Christopher Adetuberu to n se agunbanirọ niluu Ogbomọsọ, nipinlẹ Ọyọ, lọ siwaju ile-ẹjọ lori ẹsun pe o n lo ori ẹrọ ayelujara lati fi lu ọpọ ti ko mọwọ mẹsẹ ni jibiti pẹlu oniruuru ẹri niwaju ile-ẹjọ.

 

 Adetuberu gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, o ni lati ọdun 2016, ni oun ti bẹrẹ iẹ Yahoo-Yahoo ie.

Nigba ti Onidaajọ Ibrahim Yusuf n gbe idajọ rẹ kalẹ, o ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii ati awọn ẹri to daju, Adetuberu jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, ko lọọ sẹwọn ọdun meji pẹlu iẹ aekara tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun lọna igba Naira (200,000). Ki gbogbo dukia ti wọn ba lọwọ ati owo ti wọn ba ni akoto ounwọn rẹ di tijọba apapọ.

Leave a Reply